Soji Amosu |
Nibi ibo to
waye naa ni okunrin naa ti fibo e la awon meji yooku ti won jo n dije mole,
tawon yen si subu yakata pe awon ti gba fun Amosu gege bi oga won.
Awon meji
yooku ti won fidi remi ni Arabinrin Oluremi Olugbenro to wa lati ileese redio
Paramount ati Abiodun Ogundipe toun wa lati ileese redio OGBC.
Loju ese ti
won ti kede pe Amosu lo jawe olubori nibi ibo naa ni Biodun Ogundipe ti gba fun
Olorun pe akoko si wa lojo iwaju lati depo naa, nigba to ki alaga tuntun naa ku
oriire.
Nigba ti
Arabinrin Remi Olugbenro toun wa lati ileese Radio
Paramount toun fidi jale
nibi ibo naa si daa si agidi pe oun ko gba abajade esi ibo naa.
Obinrin yii
la gbo pe won ni alaga to sese fipo naa sile, Wole Sokunbi faa kale lati dije
fun ipo alaga, eyi tawon omo egbe oniroyin fibo won so lojo naa pe awon ko le
gba iru nnkan bee wole.
Ninu oro
Soji Amosun, alaga tuntun naa lo ti dupe lowo awon omo
egbe fun igbagbo ti won
ni ninu oun lati dibo yan-wole, o wa seleri pe oun ko ni doju ti won.
Nibi ibo naa
ni won tun ti dibo yan Kunle Olayeni gege bi igbakeji egbe naa, Kunle Ewuoso ni
akowe egbe tuntun nigba ti Abiodun Taiwo je igbakeji e. Anthony Gadonu ni akapo
egbe naa nigba ti Abiodun Lawal je ayewe owo wo. Gbogbo won ni won si ti sebura
fun-un lojo naa.
No comments:
Post a Comment