Lojo Aje, Monde, tii se ojo kin in ni, osu kerin ni igbejo yoo bere lori ejo ti egbe oselu Labour, nipinle Ogun, pe ajo eleto idibo lori bi ko se si oruko oludije egbe oselu naa ninu ibo gomina to waye lojo kesan-an, osu keta, ti won si n bebe fun atundi ibo naa.
Lose to koja ni egbe oselu naa gbe ajo eleto
idibo ati egbe oselu All Progressive Party ti won wole ninu ibo naa loo sile
ejo,eyi ti won pe nomba e ni EPP/06/GOV/02/2019.
Eyi ti won ti ro awon adajo to n gbejo naa
lati pase pe ki won gba iwe eri mo ti di gomina tajo INEC fun Dapo Abiodun to
wole nibi ibo naa.
Bee ni won tun ro won ki won pase fajo INEC
lati seto ibo gomina mii-in laaarin ojo mokanlelogun sakooko yii. Ninu atejade
kan ti Nyor Henry Sekula, to je akowe olugbejo naa fi sita, to si tun fowo si,
lo ti so pe ko si aye lati fi akoko sofo, ojo Aje, Monde, ose to n bo yii ni
igbejo yoo bere, kawon toro naa kan si wa ni imurasile.
Kehinde Ayanwale to je agbejoro olupejo ni won
fi leta naa sowo si, lojo kerindinlogbon, osu yii.
Ogbeni Sunday Oginni, to je akowe egbe naa
nipinle Ogun atawon meji mii in la gbo pe won kowo bowe ipejo naa loruko egbe
oselu Labour.
No comments:
Post a Comment