Egbe oselu All Progressives
Congress (APC) ni ipinle Ogun ti sapejuwe ibo gomina to waye lojo kesan-an, osu
keta, to gbe Omooba Dapo Abiodun wole gege bi gomina, je erongba tokan tokan
awon omo ipinle naa.
Ninu atejade ti akowe ipolongo egbe
naa, Tunde Oladunjoye, fi sita lojoruu, Weside, niluu Abeokuta, lo ti so pe
pelu gbogbo nnkan tegbe naa foju winna lakooko ipolongo awon omo ipinle naa
jade lati fi ibo won soro pe Dapo Abiodun lawon fee ni gomina fun odidi odun
merin mii in.
Gege bo tun se wi, o ni ibo egberun lona
aadojo o le mejo lo fi ju ti tawon omo ile igbimo asofin tiluu Abuja ti won
koko di lo, eyi to tumo si pe awon omo ipinle Ogun mo on mo pinnu lati dibo yan
gomina ni..
O tun salaye siwaju pe ko siyemeji
ninu e pe oludije won, Dapo Abiodun,
fajulo han daadaa gege bi awon oludije yooku se so lori ibo to waye naa.
Bee ni Oladunjoye tun so ninu atejade
naa pe ko tii si ninu itan ibo ipinle Ogun pe kawon oludije gomina ranse ikini
ku oriire pelu atileyin nla bayii iru eyi ti Dapo Abiodun gba latigba to ti
wole, nibi tawon bii Omooba Buruji Kashamu, Omooba Gboyega Nasir Isiaka, Otunba
Rotimi Paseda, Oloye Tope Tokoya, Ogbeni Adewale Omoniyi atawon mewaa mii in ti
wa ki i ku oriire.
Lori igbejo lori ibo to waye,
Oladunjoye lawon ro egbe oselu Allied Peoples’ Movement APM lati dake fun
ipolongo ti ko nitumo nipa igbejo to fee bere naa, o ni ki won fun ofin laaye
lati sise e.
O ni akosile wa pe ida aadorun awon
towo te fun asemase lakooko ibo naa ni won je omo egbe oselu Allied Peoples’
Movement atawon to n sise po pelu ijoba
to wa lode yii ni gbogbo ona lati sojooro lakooko ibo naa
O wa pari oro e pe itiju nla lo je
fun Gomina to wa nibe bayii ati egbe oselu APM pe pelu gbogbo owo ti won na,won
ko tun le mu ida kan ninu ida meta ijoba ibile.
O lo da oun loju pe bi ibo gomina ba
tun maa waye ni igba, igba Dapo Abiodun ni yoo tun wole.
No comments:
Post a Comment