Egbe oselu Labour nipinle Ogun ti ro ileejo to n gbejo lori ibo gomina to waye lojo kesan-an, osu keta, lati fagile ibo to waye naa, eyi to gbe Omooba Dapo Abiodun wole gege bi gomina nitori bi won se yo oruko oludije, ami egbe won kuro ninu iwe idibo lojo naa.
Ninu iwe ipejo ti Arabinrin Modupe Sanyaolu, to
je oludije gomina naa ati egbe naa lapapo ko ti nomba e je, EPP/06/GOV/02/2019,
ni won ti be ileejo lati gba iwe eri to
da oludije gomina labe egbe oselu APC iyen Dapo Abiodun pada. Ki ajo INEC si seto ibo mii-in laipe yii.
Awon ti oniroyin wa gbo pe won pe lejo naa ni
Dapo Abiodun,to wole ibo gomina naa, AbdulGaniy Raji, to je olori ajo INEC
nipinle Ogun ati ajo INEC lapapo.
Ogbeni Sunday Oginni, to je akowe egbe naa nipinle
Ogun atawon meji mii-in la gbo pe won kowo bowe ipejo naa loruko egbe oselu
Labour.
Eda iwe ipejo naa ti won fi sowo si wa lo tun
ti so di mo pe ojo mokanlelogun ni ro ileejo naa lati pase fun ajo INEC lati
seto ibo gomina mii in nipinle Ogun.
A o ranti pe ibo gomina to waye nipinle Ogun
naa lo gbe Dapo Abiodun to wa latinu egbe oselu APC wole lojo keesan-an, osu
keta, odun yii.
No comments:
Post a Comment