Ta ni yoo di alaga fegbe awon oniroyin ipinle Ogun?. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 26 March 2019

Ta ni yoo di alaga fegbe awon oniroyin ipinle Ogun?.




Lojo Eti, Furaide, ose yii ni egbe awon oniroyin nipinle Ogun iyen Nigeria Union of Journalist, NUJ, yoo seto ibo lati yan awon adari tuntun ti yoo tuko egbe naa fodun meta.

Idibo naa ni yoo waye ni oluulese egbe naa to wa ni iwe iroyin, Oke- Ilewo, niluu Abeokuta. Awon meta ni won jade lati dupo alaga egbe naa, awon naa ni Soji Amosu, eni to si je akowe egbe naa titi di akoko yii,ileeese itaniji taa mo si National Orientation Agency, NOA lo ti n sise.


 Arabinrin Oluremi Olugbenro toun naa ti dipo mu ninu egbe naa tele, gege bi igbakeji akowe egbe, to si wa lati ileeese redio Paramount.

Abiodun Ogundipe toun naa wa lati ileese redio OGBC naa so pe bi won ba le foun laaye, oun naa fee se alaga egbe naa ninu ibo to n bo lona naa.

Bee lawon mii in tun jade lati dupo igbakeji alaga, akowe ati igbakeji akowe, awon tomo egbe ba si dibo fun, to gbegba oroke naa ni yoo dari egbe naa.


Bo tile je titi di akoko yii lokan awon oludije naa ko tii bale nitori won ko mo boya awon ni won yoo dibo fun tabi elomii in, idi niyi to fi je won ko ti nisinmi, won ko si mo ibi toro ibo naa yoo ja si.

Iwadii fi ye wa pe awon meji ninu awon oludije naa lawon eeyan si n foju si lara nigba ti eniketa naa si ni ireti pe boya iyanu le sele lojo ibo naa, nitori naa loun atawon eeyan e ti won jo n se ipolongo naa ko fi rewesi, ti won si fohun gbogbo le Olorun lowo.

Ibeere wa ni pe ta ni yoo wole fun ipo alaga fawon oniroyin, nitori bi won se ni Soji Amosu se n leri  bee naa ni Remi Olugbenro naa so pe oun yoo fi nnkan ti won n pe ni obinrin han-an.


Bakan naa ni Abiodun Ogundipe so pe loooto  loun tutu loju sugbon ki i se bee naa loun tutu nipa ibo to n bo na. Gbogbo awon ileeese iroyin to wa labe won, ti won yoo kopa nibi ibo naa ni won ti n se ipolongo de.

Bawon kan se n so pe awon ko fee kawon to ti wa nijoba lati bi odun meloo kan seyin ninu egbe naa pada bee lawon kan tun so pe awon ko fee ki eni to je alaga egbe naa to fee fipo sile fa eeyan kale pe dandan oun ni ko wa se alaga egbe naa, won ni bigba to ni asiri ikoko ti ko fee ko tu sita, lo se fee fa oludije kale pelu tipa.

Pelu gbogbo e naa, ojo Eti, Furaide, yii naa ni ooto yoo foju han tawon omo egbe yoo fibo gbe eni ti won n fee wole.







No comments:

Post a Comment

Pages