Ope o;Egbe osere tiata TAMMAN naa gba iwe eri lodo ijoba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 21 March 2019

Ope o;Egbe osere tiata TAMMAN naa gba iwe eri lodo ijoba
Egbe osere tiata  ti won pe ni Theatre Artist Movie Maker and Marketers Association iyen TAMMAN la gbo pe awon naa ti gba iwe eri, ti won si ti da duro gege bi egbe kan lorileede yii.

Gege bi Isiaka Odutola, topo mo si Omiogbon to je alaga igbimo agba egbe naa se wi, O ni awon gba iwe eri egbe naa ti nomba e je 121367 labe CAC.

Nigba to n soro nipa egbe naa, Okunrin naa so pe idasile e waye lori bawon agba kan ninu ise tiata se n lo owo agbara, ti won ko si bikita lati gbe awon to wa leyin won dide.

O salaye pe egbe TAMMAN wa lati wa isokan eyi to ti sonu laaarin awon osere tiata nipase gbigbe owo agbara le awon to je omo egbe onitiata yooku lori.


Alaga igbimo agba egbe osere tuntun naa tun so pe gbogbo ona lati maa gbo ooto, eyi to fo egbe ANTP si wewe. O ni okan lara nnkan to je won logun ni lati sawari awon agba osere ti won ti pa ti.

O ni bee lawon tun gbero lati daa duro, lati maa ta ise ti won ba gbe jade funra won lati dena ere apajude tawon maketa maa n fi won pa.

O ni erongba rere ni egbe osere tuntun, inu awon si dun pe egbe osere TAMMAN se itewogba lodo ijoba pelu iwe eri ti won gba naa.

Bee lo ni igbese ti n loo lowo lati fopin si awon to n ji ise onise iyen copyright.


  

No comments:

Post a Comment

Pages