Boroboro bi aje ni Odomokunrin kan,
eni odun meedogbon, Ajibade Olumuyiwa, n ka ni ogba awon olopaa to wa ni
Eleweran niluu Abeokuta lori esun pe o pa Arakunrin toruko e n je Olakiitan
Balogun, eni to so pe oun ka mo ori iyawo oun nibi ti won ti n ko ibasun fun
ara won.
Gege bi a se gbo, laaarin oru, ni
nnkan bi aago mejila abo, lojo ketadinlogun, osu keta, ni won so pe isele naa
waye ladugbo Donland, Ajuwon nigba ti won ni sadeede ni Ajibade denu ile e lati
wa sun.
Sugbon siyalenu e, okunrin ti won pe
ni Balogun to je ale iyawo e yii lo ba nile, nibi tawon mejeeji ti n kona si
ara won ni abe, ti oru si ti dabo.
Igbadun kinni ti won n se yii, ko je
ki won tilekun lale ojo naa, eyi ti ko je ki won mo pe oko iyawo ti de, lojiji
ti won fee maa dide ni won ri Ajibade, ti iberubojo si daa bo won.
Pelu ibinu nnkan to ri ni won si pe
Ajibade fi bere ija pelu ale iyawo e yii, to si le ori e mo ogiri, nibe ni
Balogun gba de ajule orun, to ku lojiji.
Ariwo o o ti paayan lawon ara inu
ile naa gbo ti won fi jade, ti won si ba oku Balogun nileele, ki Ajibade ma baa
salo ni won se sare loo si tesan awon olopaa to wa ni Ajuwon loru ojo naa.
Oga olopaa agbegbe naa to n je Afolabi
Kazeem lo saaju awon omoose e lo sibi
tisele naa ti waye ti won si mu Ajibade loju ese.
Nigba ti Ajibade n jewo fawon olopaa
ninu iwadii won lo ti so pe oun fee wa sun tiyawo oun lojo tisele naa waye loun
ka ale ati iyawo nibi ti won n ko ibasun funra won daradara.
Ibinu toun bii lo je koun le ori mo
ogiri to fi ku. Sugbon iyawo ni tie, Titilayo Olayiwola so pe iro loko oun pa,
okunrin naa ko ba oun ni asepo. O so pe lati nnkan bii osu mejo loko oun ti sa
kuro ninu ile, to pa oun ti. O ni se lo pase fun geeti maanu awon lati maa so
oun kaakiri boya o le ri okunrin pelu oun.
Titilayo tun so pe’ Se e ri lojo
tisele naa waye, okunrin to pa yii, bata lo n tun se, ile wa ko jinna si ra
won, nitori a tun sun mo ara wa daadaa.Orebinrin e lo wa a wa lojo naa nigba to
si je pe oun nikan ko lo n daa gbe lo se ni ko maa bo lodo mi. Loju ese ti Geeti
maanu yii rii pe okunrin naa wa sodo mi, lo pe oko mi lori foonu’
O ni bo se wole, ko gbo nnkankan
lenu oun ati orebinrin Ajibade to fi bere si ni na-an, to fi di pe o le ori e
mogiri niyen, to si ku patapata.
Agbenuso awon olopaa nipinle Ogun,
Abimbola Oyeyemi ti wa so pe awon ti gbe oku okunrin naa loo si mosuari, bee lo
ni komisanna awon olopaa nipinle Ogun Ahmed Iliyasu ti pase pe ki iwadii te siwaju lori isele naa
niwongba to ti wa ni Eleweran niluu
Abeokuta.
No comments:
Post a Comment