Oloogbe Yemisi Senfuye |
Akoko ta a wa yii ki i sakoko to dara nile ijosin ile isura Olorun iyen Treasure House of God, to wa ni Quarry, niluu Abeokuta nitori bi iyawo oludasile ijo naa, Arabinrin Yemisi Senfuye se ti dagbere faye pe o digbose.
Gege bi a se gbo, ni aaro yii ni
obinrin toun naa je iranse Olorun pa oju de,n pe e ti ko le dahun mo, ki
won si to mo nnkan to sele, Arabinrin Yemisi Senfuye ti loo je Olorun nipe, o
si ti pari ise re ninu aye yii.
Obinrin yii ni o je iyawo oludasile
ijo naa, iyen Pasito Seye Senfuye. Won so pe aisan ranpe die bayii lo se
obinrin naa, laimo pe olojo ti de.
Arabinrin Yemisi Senfuye ni won
sapejuwe gege bi abiyamo tooto, to tun je olufokansin ninu ile Olorun. Opo awon
to mon on ni won so fun oniroyin wa pe onirele obinrin ni pelu.
Gbogbo bi eto isinku yoo ba se maa lo ni
a o fi maa to yin leti laipe.
No comments:
Post a Comment