I show Snr |
Gbajumo olorin juju nni, Victor
Olagoke Oluwasola Ogunsola topo mo si I Show Senior ti so pe ise orin to n ko
ki i se ayaba rara nitori nnkan toun jogunba, nitori baba to bi oun, to je agba
osere tiata, ko to ku, iyen Ishola Ogunsola, agba olorin ni, ninu ebun orin naa
loun ti jogun.
Osere olorin juju naa soro yii
lakooko to n ba oniroyin wa soro laipe, o so pe ise orin je nnkan toun nifee si
lati kekere, ati pe bi Olorun se fun baba oun lebun e bee lo fun oun naa.
O salaye pe lati soosi baba oun loun
ti sawari ebun orin naa, bo tile je pe nigba toun dagba, ipa ona orin juju loun
yaa si toun si n ko titi di akoko yii.
Goke olorin juju naa tun so pe bo
tile je pe opo ipenija loun ti baa pade nidii ise ohun sugbon oun dupe pe
igbagbo oun ko ye, nitori iforiti ati suuru.
O ni oun dupe pe Olorun ti gba owo oun
gbe kaseeti orin merin jade tawon eeyan si tewogba a ati pe ko si eyi to kuta
ninu awon orin naa, nitori pe ise opolo ni. Awon kaseeti to so pe oun gbe jade
naa ni My Joker, Thanksgiving, God of miracle ati Appreciation
Bee lo tun so pe gege bi iriri oun,
ko si ise teeyan ba fee se, yoo fee ruju bi eni pe o fee yo lemi e sugbon sa,
nipase adura, iyanu a sele.
O fi kun oro e pe nitori ife ati
ebun toun ni si ise orin juju, iyen ni ko je koun nise mii in toun si gbaju mo
daadaa titi di oni, nitori ise to ni ojo iwaju ni feni to ba fi tokantokan se.
Omo I show Pepeer tun so pe ninu
egbe onijuju nipinle Oyo, oun ko see fowo ro seyin, toun si kopa to joju nibe.
O wa ni ko sigba kankan tinu oun baje ri nitori pe ojoojumo ni inu omo Olorun maa
n dun.
O ni bo tile je pe oun ko le gbagbe
ojo toun ni ijamba moto sugbon, to ku die ki ese oun baa rin amo ori ko oun yo,
O wa ni ki awon ololufe e oun maa fadura ha noun lowo, nitori opo ise orin
tawon eeyan ko tii gbo ri loun fee maa gbe jade, fun igbadun won.
No comments:
Post a Comment