Eyin banki eti yin meloo, eni to ba ya Amosun lowo lakooko yii fowo se saara ni o- APC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 18 March 2019

Eyin banki eti yin meloo, eni to ba ya Amosun lowo lakooko yii fowo se saara ni o- APC

Egbe oselu All Progressives Congress ( APC ) tipinle Ogun, ti so fun gbogbo ileese banki lati gba akiyesi lati akoko yii loo, nipa yiya Gomina Ibikunle Amosun lowo, nitori banki to ba se bee, kan fee wo gau ni, nitori saara nla ni.

Ninu atejade ti Ogbeni Tunde Oladunjoye, to je akowe ipolongo fidihe fun egbe naa fi sita lo ti so pe banki tabi ileese isuna to ba gba abawole lati yaa lowo kan ko ara e sinu ewu ni.

Gege bo se wi, o lawon gbo pe gomina to ti n mura lati maa kogba nile bayii ti n gbindanwo lodo awon banki kan lati ya owo loruko ijoba leyin igba ti Dapo Abiodun ti won sese dibo yan ba gbajoba.

O tun salaye siwaju pe “Awon tun gbo pe opo iwe to je mo ti ijoba ni won ti palemo e kuro ni ofiisi gomina pelu ase lati odo Gomina Amosun. Nnkan to se pataki lati je kawon osise toro naa kan mo ni pe ise  won ni lati toju awon iwe to se pataki to je tijoba’

O tun so pe ohun tawon fee je kawon banki mo ni pe ijoba to n bo yii nigbagbo ninu ofin, nitori idi eyi isakoso ijoba ko nii gba owo ti ko ba ni ipase rere ti won fi gba lowo won.

O ni owo tile igbimo asofin ipinle Ogun ko ba fowo si, awon ko ni san an fun banki kankan.


No comments:

Post a Comment

Pages