Ka ni Olorun dabi eeyan ni, mo le ma depo gomina- Dapo Abiodun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 18 March 2019

Ka ni Olorun dabi eeyan ni, mo le ma depo gomina- Dapo Abiodun



Gomina tuntun ti won sese dibo yan nipinle Ogun,  Omooba Adedapo Abiodun, ti so pe ka ni Olorun dabi awon eeyan ni, o se e se koun ma wole fun ibo gomina to waye laipe yiii sugbon oun dupe pe Olorun fi ajulo e han awa eda.

O soro yii nibi isin idupe to waye lojo Aiku, Sannde, ana, ni
soosi St. James Anglican Church, to wa ni Iperu, nipinle Ogun. O so pe oun to je koun maa duro ti opo ipenija toun ti koju ninu aye yii ni ti igbagbo toun ni ninu Olorun, eyi to si fese e mule ninu Bibeli iyen Mark  ori kokanla ese ketalelogun.

Dapo Abiodun so pe oun dupe lowo Olorun fun abo ati isegun e lakooko ti ipolongo naa waye. O mu wa si iranti ijakule to ba pade lodun 2015, nigba to dije fun ipo seneto ni ekun Ogun East sugbon o ni oun ko je ki o ko irewesi ba oun, pelu ireti toun ni pe ojo iwaju oun yoo si dara ninu oselu.

O wa seleri pe isejoba oun yoo mu igbe aye rorun fun gbogbo awon olugbe ipinle naa bee ni anfaani yoo wa fawon to ba fee da ise sile, ti yoo se pese ise fawon ti ko nise lowo.

Gomina tuntun ti won sese dibo yan naa tun salaye siwaju, o so pe” Bi mo se saseyori ninu ibo taa di koja yii, ise Olorun ni. Awon ore mi atawon to yi mi ka n beeere lowo mi pe, Dapo, ki lo mu o, te siwaju ninu irinajo oselu, ki lo n gbenu okan e? Sugbon mo duro ninu igbagbo, mi o je ko ye. Iwo to ba fee se aseyori ninu nnkan, o gbodo duro, ma se je ki igbagbo e ko ye’.
O so pe ninu emi oun, oun ni erongba rere fun orileede oun, oun ko siyemeji, idi niyii ti Olorun fi mu erongba oun yii se.O ni “  Ni nnkan bii odun meloo kan seyin ti mo pada de lati yunifasiti, won fun mi ni oore-ofe lati sin ipinle Ogun, sugbon mo se ipo keji ni pamari’

Loju ese lo ni oun ti darapo mo Gbenga Daniel lati sise fun un to si di gomina. Bakan naa lo ni oun sise fun Amosun lodun 2011, to fi wole, lodun 2015, o ni won ni koun dupo seneto amo toun ko wole.
 O ni eko toun fee kawon eeyan mi loo sile ni pe nnkan ti won ba n se, ki won ma se maa so ireti ni, nitori opo ipenija ni won le ba pade.

Lara awon to wa nibe lojo naa ni Otunba Gbenga Daniel, Otunba Niyi Adebayo, Alhaji Abdulraheem Razaq, Senator Buruji Kashamu, Gbenga Kaka, Gbolahan Dada, Biyi Durojaiye, Senato Solomon Adeola (aka Yayi), Ojogbon Toyin Ashiru and Otunba Bimbo Ashiru.

Awon yooku to tun wa nibe ni  Dokita Femi Majekodunmi, Omooba Segun Adesegun, Oloye Toyin Okeowo, Oloye Tolu Odebiyi, Otunba Rotimi Paseda, Kayode Oladele atawon oba alaye.

No comments:

Post a Comment

Pages