Opo awon eeyan to gbo pe Otunba Gbenga Daniel,
oga agba olupolongo fun Abubakar Atiku fun ibo aare to koja yii, to tun ti
figba kan je gomina nipinle Ogun, ti kowe ranse si alaga egbe oselu PDP lapapo,
Uche Secondus pe oun ti dagbere fun oselu, loro naa n je kayefi fun. Ibeere
tawon oloselu naa si n beere lowo ara won ni pe se loooto ni tabi aheso.
Oro naa ki i kuku se aheso oro rara,
bo si ti ri lawon eeyan n so o pe Gbenga Daniel ti so pe oun ko se oselu mo fun
idi pataki to nitumo si oun funra oun.
Alaga egbe naa lapapo niluu Abuja,
ni okunrin naa kowe si lojo kerinla, osu yii, pe nnkan toun se ninu oselu
paapaa ninu egbe oselu PDP ti to ge, ki won je koun wa ona mii in fun igbesi
aye oun ati ebi oun, ki won je koun se gafara die.
Gege bo se wi ninu leta naa, lo ti
so pe lojo kesan-an, osu kesan- an, odun 2001, loun darapo mo egbe oselu PDP,
toun si di gomina nipinle Ogun lodun 2003, pelu ise takuntakun tawon se nigba
naa lo je kawon rowo mu lawon ipinle Yoruba marun-un nibi tegbe oselu naa ti ni
gomina. Fun odun mejo lo so pe oun fi se gomina nipinle Ogun toun si se iwon
toun le se.
Bakan naa lo tun menuba a ninu leta
e, wahala to ti n sele ninu egbe PDP lati odun 2009 si 2011 ninu eyi to mu won
padanu lodun naa lohun, to si je pe titi di akoko yii, won ko tii ri yanju.
Gbenga Daniel tun so pe’ Egbe oselu
PDP nipinle Ogun ti koju awon isoro to po ninu eyi ti onikaluku se tie lotooto,
awon asaaju wa niluu Abuja fowo mu enikan fun ibo gomina taa sese di tan yii nigba
tileejo ati ajo eleto idibo so pe oludije mii in lo bofinmu ti won ko si gba
eni ti egbe mu wole.
Eni tileeejo ati ajo INEC mu egbe ti
lee danu, awon nnkan wonyii lo sele to sakoba fun ibo gomina atii tile igbimo
asofin to waye nibi tawon ti ba ara won bayii’.
Gomina tele naa so pe oun ko kabamo
pe lori gbogbo igbese toun ti gbe ninu oselu nitori opo awon eeyan pataki lawujo
lawon jo pinnu lati fowosowopo le ijoba ti ko mu idunnu bawon eeyan. O wa ni ipinnu oun lati fi oselu sile ni lati
kojumo awon ajo toun da toun fi n ran awon eeeyan lowo.
Bee lo ni oun tun pinnu lati bere
ise pada lori ileeewe kan eyi to nii se pelu oselu ti won pe ni Political
Leadership Academy (POLA), eyi to so pe oun ti da sile lati bi odun meloo kan
seyin fun eko nipa oselu.
Latigba
tiroyin naa ti jade lopo awon araalu paapaa awon oloselu ti so ero okan won,
awon kan so pe Gbenga Daniel mon on foselu sile nitori wahala to n fojoojumo
waye ninu egbe oselu PDP nipinle Ogun, eyi ti enu e ko ka won.
Bakan naa
lawon kan so pe boya okunrin fee darapo mo egbe oselu APC nitori bo se satileyin
fun won nibi ibo gomina to waye laipe yii.
Sugbon
gbogbo bo ti wu ko ri, nnkan to daju ni pe Otunba Gbenga naa ti feyinti nidii
oselu, o loun ko se e mo, eyi tawon kan so pe yoo soro se feni ti eje oselu ba
wa lara e.
No comments:
Post a Comment