Mi o le gbagbe ojo ti oga osere tiata kan yeye mi ni lokesan- Temitope Afolabi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 14 March 2019

Mi o le gbagbe ojo ti oga osere tiata kan yeye mi ni lokesan- Temitope Afolabi


Temitope Afolabi
 
Temiitope Azeezat Afolabi okan lara awon osere tiata to n sese dide bo ti so pe ojo manigbagbe lojo ti okan lara awon agba osere yeye oun nita gbangba nitori awon jo n je oruko kan naa papo.

O soro yii lakooko to n ba oniroyin wa soro nidi ise tiata to yan-an laayo, o so pe okan lara awon oga awon toun foruko bo lasirii lo yeye oun  laarin ero nitori oun baa je oruko po. O ni o soro si oun bi eni pe Olorun ko lo seda oun toju ti oun, koda ese oun wole gerere, sugbon oun wa dupe lowo Olorun pe o fun oun ni ore-ofe lati maa dagba si nidi ise naa.

Omobinrin topo awon ololufe e tu mo si Arike tun so pe lodun 2010 loun darapo mo ise tiata lodo oga oun kan, Rasak Oyadiran tawon eeyan mo si Itu- Baroka. Nitori ise tiata je eyi toun nifee atokan wa sii.

O salaye siwaju pe fiimu toun ti kopa ninu e ti ju mewaa lo bee lo fikun oro e pe ‘Opolopo ogbon ati iriri ni mo ti ri nidi ise tiata ti mo n se, to si je pe ogbon ni mo fi gbogbo e ko’.

Opo idojuko loun ti ba pade to si je pe oun dupe lowo Olorun pe ko si eyi to bori mi oun ninu e.O wa salaye pe leyin ise tiata toun yan an laayo yii oun tun n ta aso ati bata atawon awotele okunrin lorisirisi.

O ni ‘ Nidii ise tiata yii, obinrin kan wa ti mo fi se awokose won, mo maa n gbadun won gan-an ninu awon ere ti won ba ti kopa, onitohun ni Ayo Mogaji’.
Bakan naa lo ni oun ko le gbagbe ojo akoko toun maa koko kopa ninu fiimu ti won tan ina soun loju, se lo ni eru bere si ni n ba oun, ti aya oun ja, pe kin ni iru eleyii, sugbon ni bayii awon ti jo di imule, ko si iberu kankan mo.

Nnkan to je ki ti Tope yato sawon yooku e ni pe latigba to ti bere ise tiata lo so pe awon obi oun ti fowo sii foun pe koun maa se, ti won si sadura foun pelu.

O wa lo akoko naa lati dupe lowo oga e nidi ise naa, Rasak Oyadiran, nitori o ni oga gidi to n wa ojo iwaju rere fawon omoose e nidi ise tiata ni, bee lo ni ko gba aye igbakugba fawon.

Bakan naa lo tun ni oun tun ni oga kan ti ko se foju pare, iyen Bashir Sanni fawon ipa toun naa ti ko. Osere tiata to ni oun naa wa lara awon Gallant Babes ni awon da egbe naa sile lati maa fa ara won soke nidi ise naa. Ati pe awon sese pari awon ise kan ti yoo jade laipe yii.

O wa so fawon ololufe e pe laipe yii nise oun ti yoo je akoja ewe yoo

No comments:

Post a Comment

Pages