Ode’lubadan fee segbeyawo alarinrin fomo e ni Satide ose yii niluu ibadan - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 13 March 2019

Ode’lubadan fee segbeyawo alarinrin fomo e ni Satide ose yii niluu ibadan


 
Ojo Abameta, Satide, ose yii ni gbajumo sorosoro nni, to fi ilu Ibadan sebugbe, Alaaji Kola Akntayo, topo awon ololufe e mo si Ode’lubadan yoo sayeye igbeyawo alarinrin fomo e, Opeyemi.

Gege bi iwe ipe ti won fi ranse si wa, igbeyawo naa ni yoo waye laarin Opeyemi Tohib ati Sofiat Bukola, eyi ti yoo waye ni ooteli Premier, Mokola, niluu ibadan.

Ayeye mo-mi- n-mo- o ati idana ni yoo koko waye laaaro ojo naa ni deede aago mewaa leyin naa ni ayeye igbeyawo tawon musulumi n pe ni Walimat Nikkah yoo tele, ki won to fi weje-wemu kase gbogbo e nile ni ooteli yii bakan naa.


 Baba oko iyawo, Ode Ilu Ibadan to ti figba kan je alaga sorosoro nipinle Oyo, ti wa so pe gbogbo eto lo ti to fayeye ojo naa tawon  si fa yooku le Olorun lowo.Ati pe opo awon eeyan pataki lo n bo bee lawon olorin naa yoo tun dabira lojo naa.

No comments:

Post a Comment

Pages