Olorun fajulo han Amosun, Dapo Abiodun di gomina ipinle Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 10 March 2019

Olorun fajulo han Amosun, Dapo Abiodun di gomina ipinle Ogun.Omooba Dapo Abiodun

Oro Yoruba kan lo so pe ajulo ni Olorun oba, gbogbo nnkan to wa nikawo e, ni o fi ju awa eda lo, nitori naa lo se je pe ti eda ba fee ma lo agbara lori eda egbe e, se ni yoo maa wo niran titi ti yoo fi fi agbara e han pe eeyan lasan ni.

Irufe nnkan bee lo sele lagbo oselu nipinle Ogun, pelu bi Gomina Ibikunle Amosun se leri leka to, to lo gbogbo agbara ati owo lati ma je ki Omooba Dapo Abiodun latinu egbe oselu APC di gomina ninu ibo taa sese di tan yii, sugbon Olorun jewo ara e loru mojumo yii nigba ti won kede okunriin naa gege bi eni to jawe olubori ninu ibo ojo Abameta, Satide, to koja yii.

Gege bi Ojogbon Abel Idowu, to ka esi ibo naa loruko ajo eleto idibo nipinle Ogun, se wi, O so pe Omooba Dapo Abiodun ni egberun lona orinlerugbao le eyo kan ati eedegbeta le aadorin ibo, 241, 670 nigba ti Adekunle Abdulkabir latinu egbe oselu APM ni  egberun lona ojilerugba ati metalelaadoje ibo, 222, 153.

Egbe oselu ADC nibi ti Gboyega Nasir Isiaka topo mo si GNI ti je oludije won lo si ipo keta pelu ibo egberun lona aadofa ati mejilenirinwo, 110,422 nigba ti Buruji Kasahamu to je oludije labe egbe oselu PDP ni ibo egberun lona aadorin ati oodunrun din mewaa, 70, 290.

Oniroyin wa gbo pe ibo egberun mokandinlogun ati eedegbeta le metadinlogun ni Omooba Dapo Abiodun fi ju gbogbo awon ti won dije fun ipo gomina naa lo.

Ijoba ibile mokanla ninu ogun ni Dapo Abiodun tinu egbe oselu APC ti rowo mu, nigba ti egbe oselu APM mu mefa, egbe oselu ADC mu meji, eyo kan soso to ku naa ni Buruji Kashamu ti rowo mu.

Awon ijoba ibile mokanla ti wwon dibo daadaa fun Dapo Abiodun ni Abeokuta South, Odeda, Ijebu- Ode, Odogbolu, Ijebu North East, Sagamu, Ijebu East, Remo North, Ogun Waterside, Ikenne ati Obafemi- Owode.


Awon ijoba ibile mefa tawon naa dibo daadaa fun Akinlade ti APM ni Ipokia, Ifo,  Egbado South, Abeokuta North ati Ado-Odo- Ota. Gboyega Nasir Isiaka tegbe oselu ADC rowo mu ni Imeko- Afon ati Egbado- North nigba ti Buruji Kashamu naa fajulo han won ni Ijebu- North.

Orin ope lo ti n gbenu awon omo egbe oselu APC latigba ti won ti n gbo firinfirin pe awon ni yoo jawe olubori ninu ibo, oun to si n tenu won jade ni Olorun lo fajulo han Gomina Ibikunle Amosun lori gbogbo erongba e lati ma je ki Dapo rowo mu ninu ibo naa.

Won ko tie tii kede esi ibo tegbe oselu APM ti n yari nipa esi ibo ti won ko ti I gbo, ti wwon si n hale kaakiri igboro. Amo sa, ohun to daju ni pe Dapo Abiodun ti di gomina, ojo ibura ti yoo waye lojo kokandinlogbon, osu karun un ni won n mura e sile bayii.

No comments:

Post a Comment

Pages