Dapo Abiodun |
Won ti salaye bi ile-ejo giga kan se
fagile esun ti won fi kan oludije gomina labe egbe oselu All Progressives
Congress (APC), nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun lori oro iwe eri gege bi idajo
ododo, to si je kawon eeyan nigbagbo ninu awoon adajo wa.
Ninu atejade ti agbenuso fun oludije
gomina naa, Remmy Hazzan fi sita lo ti fi idunnu e han idajo naa, eyi to fun
Dapo Abiodun lati te siwaju erongba e lati di gomina ninu ibo to n bo lojo Abameta,
Satide ose yii.
Nigba to so bi inu e se dun to lori
idajo naa, O ni oludije naa dupe lowo Olorun fun bo se gba idalare lori esun ti
won fi kan an naa, o sapejuwe idajo naa gege bi eyi ti yoo fopin si gbogbo
awuyewuye lati odo awon alatako nidii oselu lori awon oro to ti n ja nile lati
bi ojo meloo kan seyin.
O ni boun ko baa ni paro, oro naa ti
fee maa bomi sikun awon omo egbe atawon alajosisepo ninu egbe oselu APC sugbon
oun dupe pe idajo to waye naa ti fopin sii.
Omooba Dapo Abiodun wa so pe pelu bi
idajo se je ki gbogbo awuyewuye naa sinmi, oun ro gbogbo awon to ni gbon-mi-si-
omi- o- to ninu egbe naa lati wa ki won jo sise po fun aseyori egbe naa.
O wa pari oro e pe oun ti setan lati
sise po pelu gbogbo awon eeyan paapaa julo awon ti won si mo ara won gege bi
omo egbe oselu APC lati jo wa gege bi ebi kan. O wa ni onikaluku lo le ti
jajabo sugbon won lee jo segun loju ogun ti won ba jo wa nisokan.
No comments:
Post a Comment