Otunba Gbenga Daniel, to je gomina
tele nipinle Ogun ti fi atileyin e han si oludije fun ipo gomina labe egbe
oselu APC, Omooba Dapo Abiodun fun ti ibo gomina naa ti yoo waye lojo Abameta,
Satide, ose yii.
Gege bi atejade kan to fi sita lo ti
pase fawon omo eyin e lati dibo won fun Dapo Abiodun pelu, o so pe oun se
ipinnu nigba ti Ladi Adebutu ti padanu ejo ti won n gbo lowo, eyi ti idajo e
waye lojooru, Weside, ose yii.
O so pe lati nnkan bi odun mejo loun
ti dake lori oro oselu nitori awon ise egbe lapapo to wa niwaju oun bee loun
tun sa agbara oun lati rii pe Remo ni yoo tun je gomina nipinle Ogun.
Gbenga Daniel tun so pe gbogbo awon
eeyan lo ti gbo nipa abajade ileeejo, eyi ti ko gbe oun, idi niyii toun fi pase
fun gbogbo awon alatileyin oun nipinle Ogun lati dibo won fun Dapo Abiodun,
toun naa je omo Remo nibi ibo to n bo lojo Satide yii.
O wa pari oro e nipa lilo akoko naa lati be gbogbo awon eeyan
lati fi ibo won gbe egbe oselu APC wole.
No comments:
Post a Comment