Egbe oselu APC tipinle Ogun ti so pe awon ko ri bi Ladi Adebutu tegbe oselu PDP ati Abdulkabir Akinlade tegbe APM se pawopo lati jo sise po fun ibo gomina ti yoo waye lojo Satide ose yii ro lati gbe APM wole, nitori awon mo pe iya ni won yoo ba bo nibe.
Gege bi a se
gbo, losan-an yii ni Onarebu Ladi Adebutu to je oludije gomina fegbe oselu PDP
sugbon tileejo ja nitanmo pase fawon omo eyin e pe Akinlade tinu egbe oselu APM
ni ki won dibo won fun lojo naa.
Iwadii fi ye
wa pe gbogbo igbese ti Ladi omo baba Ijebu naa gbe ko se leyin Gomina Ibikunle
Amosun ati pe won ti wa lenu e tipe, idi
niyii tawon kan ninu egbe oselu PDP ti won je ti Ladi se darapo mo egbe oselu
APC ni nnkan bi ose meloo kan seyin.
Ati igba naa
lawon eeyan ti n woye pe ko ni pe ti Ladi Adebutu naa ko ni pawopo sise pelu
egbe ti Amosun ba faramo iyen APM, idi niyii toro naa ko fi bawon omo egbe
oselu APC lojiji.
Awon omo
egbe oselu APC ti so pe awon mo pe won fee lo Ladi Adebutu lati fi da ibo Remo
ru sugbon o da won loju pe ere itiju ni won yoo gba bo nibe.
May The Will of God Almighty Jehovah prevails. Amen.
ReplyDelete