Nnkan de; Awon omo eyin GNI ti sa lo si APC tan - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday, 7 March 2019

Nnkan de; Awon omo eyin GNI ti sa lo si APC tan



 
Bi a ba ni ka so tododo, akoko ti a wa yii, ki i se akoko rere fun oludije fun ipo gomina nipinle Ogun labe egbe oselu ADC, Omooba Gboyega Nasir Isiaka topo mo si GNI, o si daniloju gbangba pe igbagbo ni yoo fi maa gbe bi nnkan se n lo fun ibo ti yoo waye lojo Abameta, Satide, ose yii.

Idi abajo ni pe latigba ti esi ibo aare ati tawon omo ile igbimo asofin niluu Abuja ti waye tegbe naa ko fi bee rowo mu gege bi won se roo ni edun okan ti waye fun oludije naa.

Ohun to je pabanbari  gege bi iroyin kan ti a ti koko gbe jade lose to koja pe awon omo eyin e ti n fi egbe naa sile loo darapo mo APC.

Kekere ni won koko pe e tele sugbon ni bayii, o ti n di nnkan nla mo won lowo, titi di akoko ti a n ko iroyin yii merin ninu awon to dije fun ipo asofin ati asoju-sofin ti won ko rowo mu ni won ti fegbe naa sile bayii loo darapo mo APC lati sise fun Omooba Dapo Abiodun.

Oniroyin wa gbo pe bawon eeyan naa se n fegbe naa sile lawon eeyan won n tele won lo, bakan naa la tun gbo pe awon omo eyin Yayi ti won darapo mo ADC lawon naa ti pada si APC lodo Dapo Abiodun.

Teletele nigba ti wahala gbona ninu egbe oselu PDP nipinle Ogun laaarin Ladi Adebutu ati Buruji Kashamu gbogbo ero okan won ni pe boro naa ko ba niyanju odo GNI lawon to je omoleyin Otunba Gbenga Daniel, gomina tele nipinle Ogun yoo sise fun un, a fi bi jebete tun se gbomo le oludije gomina fegbe oselu ADC nitori bi oga won se pase fun won pe Dapo Abiodun ni ki won dibo fun.


Eyi to wa yanilenu ni pe gbogbo awon oludije  ADC fomo ile igbimo asofin ti won fee di ni Satide bakan naa, ti won ti gbemi le ibo GNI pe yoo gbe won wole ni won wa sese wa n sare to ye ki won ti sa tele.

Enikan to ba oniroyin wa soro to sunmo GNI so pe nibi toro duro de bayii, okan oga won ko bale, ko si jo pe eeyan sunkun inu lo n ba kaakiri nitoro gbogbo awon to satileyin fun un ti n pada.
Asiko yii ni won to wa n so pe awon ko le tele oludije gomina ti Oloye Olusegun Obasanjp faa kale. Hun, bi esi ibo naa yoo se lo owo Olorun nikan lo mo bayii.

A o ranti pe igba keta ree ti Gboyega Nasir Isiaka yoo jade lati dupo gomina, eemeji to ti jade ipo keta lo se lodun 2011, nigba to se ipo keji lodun 2015, asiko tawon eeyan nireti pe yoo se ipo kin in ni ni won tun fee da lagbo nu. Ori nikan lo le ko yo.


No comments:

Post a Comment

Pages