Eni ti ko ba ni itelorun ko le sise tiata- Bolanle Adejoke - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 7 March 2019

Eni ti ko ba ni itelorun ko le sise tiata- Bolanle Adejoke





Okan lara awon osere-binrin tiata tirawo e si wa nigboro nidii ise naa, Bolanle Victoria Adejoke tawon ololufe e mo si Adejoke ti so pe eni to ba fee se daadaa, to tun fee ki irawo e yo nidi ise naa gbodo ni iforiti ati itelorun ko le ba ko ogo ja.

O soro yii lakooko to n ba oniroyin wa soro, O so pe bo tile je pe ki i se tiata nikan gbogbo ise teeyan ba n se lo gbodo mo pe orisirisi ipenjia ni yoo maa ba pade sugbon to ba mo nnkan to n se yoo se aseyori nidi e.

O salaye pe loooto ki i se pe oun sese bere ise naa lati odun 2001 ni nnkan bii odun mejidinlogun seyin loun ti wa nidi e labe oga oun kan, Ogbeni Adekoya Babatunde Martin iyen nileewe giga ti won ti kose oluko iyen Tai Solarin College of Eduation, to wa ni Ijebu- Ode. Ti won n je Creative Stars Club/ ANTP, nigba naa.

O tun salaye pe lodun 2006, loun tun darapo mo egbe osere mii in ni ilu Isara Remo ti Alagba JMGO Afolabi ti gbogbo eniyan mo si Orisunmibare je adari e.

Osere-binrin naa tun salaye pe opo awon fiimu loun ti bawon kopa ninu e, lara e ni Daughters of eve,ti Tunde Lawrenceson 
Se, Mr lecturer tawon KSC group se, Together ti Femi Olawale se jade.

Awon yooku ni Wosiwonkoko tiTope Oyefeso gbe jade, Iparada, Okin, Eje Ibale, Awofelebonu, Ojo ayo, Aye Olosho, Oku alaye ,Ola Ojo, Egungun Iha oga mi  Rasak Oyadiran(Itu Baroka) lo se yen, Tori omo, Tani omo were  ati Sajuku, Baba wa Jimoh Aliu lo se yen jade ati Tori Ife  to maa jade laipe yii ti Rasak Oyadiran se.


Adejoke tun so siwaju pe titi akoko yii omo egbe osere ANTP loun toun si wa pelu awon oga oun bii Rasak Oyadiran, Bashir Sanni atawon mii in, sugbon iyen ko so pe koun maa bawon egbe osere tiata yooku sise papo ti won ba pe oun niwongba to je pe ise kan naa lawon jo n se.

 O fikun oro e pe irinajo to lagbara loun ti rin nidi ise naa, ohun toju  oun si ti ri ko se fenu so, amo kin ni kan toun mo to da oun loju ni pe oun teeyan ba n lepa, o gbodo ni ipinnu ati aforiti lee lori ko le baa debi to fee de nidi ise naa. Irufe nnkan bee loun si n se di akoko yii.

Nigba  to n menuba awon idojuko to ti baa pade, o so pe “Orisirisi lo ti je idojuko fun mi ninu ise tiata ti mo n se yii, mo ti rin de awon ibi kan ti won ti tewo gba mi,beeni mo ti de ibi ti won ti ko mi sile, sugbon sa, mo dupe lowo Olorun pe o n gbe mi soke nidi ise naa”

 O tun salaye pe yato si pe oun ni iwe eri awon olukoni lowo (NCE), oun tun ko ise asoriloge (hair dressing) pelu ise ere ori itage toun tun yan laayo.

 O wa pari oro e pe ipinnu oun ni lati gbiyanju ri pe ki gbogbo ilakaka oun nidi ise naa ko ja sasan pelu igbagbo pe oun naa yoo tipase e gbohun rere se ninu aye yii.
.
O ni oun naa ti ni egbe oun bo tile je pe oun si wa labe awon oga oun, Gallant babes  loruko egbe naa. Igbiyanju awon ni lati maa fowosowopo fa ara won lowo soke, Awon fee maa sise ni eyo kookan, pelu igbagbo pe iranlowo Olorun ati ti awon tiwon ni ife ise yii, egbe naa yoo gberu soke.




No comments:

Post a Comment

Pages