Oginni pe ejo kotemilorun lori bi won se da ejo Labour nu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 10 April 2019

Oginni pe ejo kotemilorun lori bi won se da ejo Labour nu


 
Ogbeni Sunday Oginni, to je akowe igun fegbe oselu Labour ti pe ejo kotemilorun lori bi igbimo to n gbejo lori ibo to waye se da ejo to pe nu lori bi ajo INEC ko se foruko oludije won, ati ami egbe oselu won si ibo gomina to waye lojo kesan-an, osu keta, odun yii.

Ninu ejo to pe lojo Isegun, Tusidee, sileejo kotemilorun to wa niluu Ibadan lo ti lawon ko gba idajo ti igbimo to n gbejo naa da niluu Abeokuta lori ejo e ti won danu.

O ni ejo naa ti nomba e je EPT/OG/GOV/02/2019 lo ti salaye pe awon ti sanwo to ye kawon san lakooko tawon kowe ipejo koda awon ti san ko to di pe Abayomi Arabambi pe ejo tie ti nomba e je EPT/OG/GOV/03/2019.

O tun so pe o ye kawon igbimo naa fagile le ejo ti alaga egbe oselu Labour ti nomba e je EPT/OG/GOV/03/2019 nu  nitori o lodi si ofin igbese ipejo nileejo.

Gege bi Oginni se so, o fi aidunnu e han lori igbese ti igbimo to n gbejo naa, o ni o ye ki won ye iwe ipejo naa wo finnifinni ko to di pe won pinnu lati daa nu.. 

O ni ‘Mi o gba ejo ti nomba e EPT /OG/ GOV/02/ 2019 lati fi ropo EPT/OG/GOV/03/2019 ti igbimo to n gbejo naa da nu wole rara nitori e ni mo se pinnu lati pejo kotemilorun siluu Ibadan’.


‘Leyin ojo karun un ti mo pejo ni tawon ti igun Arabambi pe ti won. Ejo mi nikan ni won ko sile lati gbo. Gbogbo e lo wa lodo igbimo to n gbejo naa. Alaga to n gbejo so nigba taa koko bere ijokoo beeere fun iwe owo idabobo lati gbe igbese lori ejo taa pe, taa si se pelu egberun lona irinwo naira taa san fun won’.

O ni nnkan ti ko ye awon ni pe ki lo de ti igbimo naa da ejo won nu leyin tawon ti san owo ti won beere lowo awon ti won pe lowo idabobo.

Lojo Isegun, Tusidee ni Adajo Chinwe Onyeabor  to saaju igbimo to n gbejo naa da ejo ti Oginni Olaposi, pe nitori to so pe iru ejo yii kan naa ni Abayomi Arabambi to je alaga igun mii in ati Arabinrin Modupe Sanyaolu to je oludije gomina ninu egbe pe.  .No comments:

Post a Comment

Pages