Awon ajomogbe |
-Atimole olopaa ni won wa bayii
Owo awon olopaa nipinle Ogun ti te awon
meta kan, Kate Njoku Joy Okorie ati Onyeka Joseph toun je okunrin ninu won lori
esun pe won maa ji awon omo gbe lodo awon obi won, ti won si tun maa n ta won.
Gege bi iwadii oniroyin wa, se ni won
so pe awon eeyan naa maa n da ogbon pe oko ati iyawo ni won, ti won yoo loo gba
ile lati maa gbe papo gege bi toko-taya.
A gbo pe ile tawon omode ba ti po si
ni won saaba ti maa n dan iru asa bee wo, ti won ba si ti ri pe won ti wole
sawon to n gbe ni adugbo naa lara daadaa, ni won yoo jawon omo won gbe ti won
yoo si loo ta won niluu ibomii-in.
Iru e ni won lo sele sawon towo te
naa, gege bi Abimbola Oyeyemi, to je agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun, se wi,
o lawon omo mejo lawon towo te naa ti ji gbe lawon agbegbe kan nipinle naa ti
won si pinnu lati ta won fawon onibara won nipinle Anambra.
Awon omo ti won ri pada |
O so pe eka awon olopaa to n ri si
jiji omo gbe ati egbe okunkun ni won sise takuntakun nigba ti won topase
obinrin kan toruko e n je Mary Paul ti won lo je oga won nidii ise naa loo si
ipinle Ondo nibi to ti n jejo lowo.
Pelu ifowosopo ileese awon olopaa
ipinle Ondo ni won so pe owo fi te awon meta towo te naa, ti won si fesun kan
won pe won lowo ninu awon omo mejo ti won ji gbe naa. Meta ninu awon omo mejo
ti won ji gbe, ni won ti gba a pada lowo won.
Okan ninu awon omo naa ti won ti ri toruko e
n je Temidayo Ajayi la gbo pe won ji gbe
pelu egbon e ninu osu keje odun to koja niluu Sagamu. ni won ti da pada fawon obi e, o ni igbese si
n lo lowo lati ri egbon e pada.
Agbenuso awon olopaa tun salaye pe awon towo te naa ti n fowosowopo pelu awon olopaa lori bi won se ji awon omo gbe
ati bi won se n ta won fawon onibara won nipinle Anambra.
Komisanna awon olopaa nipinle Ogun,
Bashir Makama ti wa pase pe ki won ma se foro awon towo te naa fale, ki won
bere iwadii lati le sawari awon yooku ti won jo n sise po.
Bee lo ro awon obi lati maa setoju
awon omo won daadaa lati ma se fi won sile fun ajeji eeyan.
No comments:
Post a Comment