Ojo Eti, Furaide, ni ayeye isinku
agba onkowe nni, Alagba Oladejo Okediji, yoo waye niluu Oyo.
Gege bi atejade kan to te wa lowo,
irole oni, Ojobo, Tosidee, ni asale isin awon onigbagbo yoo waye ni soosi
Methodist, to wa ni Apaara, niluu Oyo,
legbe ileewe alakoobere Methodist.
Nigba ti isin akanse isinku yoo si
waye laaaro ojo keji, bere ni deede aago mewaa aaro nile ijosin yii bakan naa.
Aaro Ojoruu, Wesidee, ni Alagba Oladejo Okediji jade laye leyin ti won ti lo
odun mokandinlaadorun laye.
Ninu oro Ogbeni Arigbabu Ibrahim omo Ajanlekoko, baba je onigbagbo daadaa, ti won ko eeyan mora, awon nnkan ti won so fun mi nigba ti mo de odo won lodun to koja lo.
Won so fun mi pe ewi ti mo n ke naa ni ki n maa ke lo, ki n gbiyanju
lati maa ta asa Yoruba ji, won ni bawon ba si wa lori eepe, awon yoo je ki n dabi awon bii Adebayo Faleti, Lanrewaju Adepoju atawon mii in.
ÌTÀN
ÌGBÉSÍ AYÉ OLÓÒGBÉ OLÓYÈ OLÁDÈJO ÒKÉDÌJÍ gege bi Ààre Soliu Babátúndé Salaudeen, se salaye e.
Ìdílé onígbàgbó ni Olóyè Oládèjo
Òkédìjí ti wá. A bí i ní ìlú òyó, tíí se ìlú bàbá rè ní ojó kerìndínlógbòn, Osù
kewàá odún 1929.
Òun ló sìkejì omo méta tí ìyá àti
bàbá rè bí. Ìlú òyó ni Oládèjo Òkédìjí ti lo ìgbà èwe rè. Nígbà tí ó di omo
odún méfà ni ó bèrè ilé-ìwé.
Ó lo sí ilé-ìwé ìjo elétò ti Àpáàrà, òyó,
láàrin odún 1935 sí 1941. Ó tún lo odún méjì ní ilé-ìwé Ándérù mímó ní ìlú òyó
Kan náà.
Léyìn ìwé méfà, ó se isé olùkó ní
Fìdítì, létí òyó, kí ó tó lo lo odún mérin ní Wesley college, ìbàdàn
(1945-1948), láti kó isé olùkó onípò kejì. Òkédìjí kò dúro se isé olùkó ní
agbègbè òyó mó léyìn tó ti parí èkó rè ní odún 1948.
Díè nínú àwon ìlú tó ti se isé olùkó ni;
Ìjèbú-òde, òwò, Èkó, Àkúré, àti Ilé-ifè. Ní sáà ètò èkó odún 1975/1976,
Yunifásítì Ilé-ifè gba Oládèjo Òkédìjí láti kó èkó odún kan fún ìwé-èrí olùkó onípò-kínní.
Oládèjo Òkédìjí se ìgbéyàwó ní odún 1953; omo Ìdó-Àní létí Òwò ni ìyàwó rè,
Christiana Omolara. Omo márùn-ún; obìnrin mérin àti okùnrin kan ni Olórun fi ta
wón lóre.
DÍÈ LÁRA ÀWON ÌWÉ TÍ OLÁDÈJO ÒKÉDÌJÍ
KO.
1. Àjàlólerù (1969).
2. Àgbàlagbà Akàn (1971).
3. Atótó Arére (1981).
4. Ògá Ni Bùkólá (1972).
5. Réré Rún (1973).
6. Ìmúra Ìdánwò Yorùbá (1979).
7. Sàngó (------).
"Bí Onírèsé ò bá fíngbá mó, èyí
tó ti fín sílè ò lè parun."
|
No comments:
Post a Comment