Lawrence Oyedokun, to je omoose agba osere tiata nni, Yinka Quadri atawon meji mii in, Rebecca Oyebode ti won pe ni orebinrin e ati Oyewunmi Abiodun Ridwan ti won pe ni ore e ni won ti wa ni tesan awon olopaa lori bi won se foruko agba olorin juju, King Sunny Ade lu jibiti towo e tomilionu Naira.
Won ni se lawon
afurasi naa loo si ero ayelujara Instagram ti kingsunnyademusic
nibi ti won ti polowo
ayederu irinajo lati loo sere ni U.S ati U.K
Oniroyin
wa gbo pe aimye owo ni Oyedokun atawon
eeyan e yii ti ko jo nipase fifi oruko okunrin agba oje olorin naa lu awon
eeyan ni jibiti.
Nigba to n soro nipa
isele naa, King Sunny Ade, so pe se lawon
eeyan n pe oun pe awon gbo pe oun murasile lati rin irinajo lati korin.
O fikun oro e pe nigba
ti ipe naa n po lapoju loun se foro naa to awon olopaa leti lati ran oun lowo. O
ni ero awon eeyan ni pe boya oun loun se nnkan bee laimo pe oun ko se iru e ri
laye oun.
O ni nitori pe oun je
eni to pa ofin mo loun se foro naa to komisanna awon olopaa leti pelu ileri pe
awon yoo se iwadii. A gbo pe Oyedokun ti won fesun kan naa ko jade nileewee
awon olukoni iyen Osun State College of Education,
Ilesha, to lo, won ni yara ikekoo keji
lo wa to fi kuro.
Ninu osu keta odun to
koja ni won so pe o ti n foruko Sunny Ade lu jibiti, milionu meta naira ni won
lo ti gba lowo awon bii mokanlelogota eeyan.
Ogba awon olopaa lo si
wa titi di akoko, ti iwadii si n tesiwaju.
No comments:
Post a Comment