Won losere-binrin onitiata kolu Ojopagogo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 18 April 2019

Won losere-binrin onitiata kolu Ojopagogo


-lokunrin naa ba niro ni

Iroyin to gba gbogbo igboro kan ni pe aisan nla kan ti kolu gbajumo osere tiata nni, Razaq Olayiwola, topo awon oloolufe e mo si Ojopagogo, won so o debi pe aisan naa lowo aye ninu debi pe ile iwosan lo wa nibi to ti n gba itoju.
Sugbon osere omo bibi ilu Iseyin,nipinle Oyo so pe oun ko si ninu idubule aisan o, ati pe koko lara oun le, toun si n je amala lowo.
Gege bi a se gbo,ni nnkan bi ose meloo kan ni Ojopagogo pe lokesan kan siluu Oyo, nibi to ti n ya fiimu tuntun,oun gan-an lo dari ise ti won se naa.
Ibi ti wahala naa ti bere ni bi won lo se fi osere-binrin mii in ropo eni ti won lo tele ti won lo kopa to joju ninu fiimu ti won ya lowo naa,nitori won ni ko mu nnkan ti won ni ko se naa daadaa.
Ale ojo naa ni won ni aisan nla naa kolu Ojopagogo ti won si sare gbe loo si osibitu Saint Michael, to wa ni Owode, niluu Oyo. Ose meji ni won so pe o lo nibe, ki won to fi sile.
BO SE RI tun gbo pe won ni obinrin onitiata so fun okan ninu awon ore pe oun loun wa nidii aisan to n se agba osere naa,bo tile je pe a o fidi e mule sugbon won nibi to ti n soro naa lawon to sun mo Ojopagogo ti gbo ti si ti so fun un.


Aheso tawon eeyan n gbe kaakiri pe osibitu ni Ojopagogo wa nibi to ti n gba itoju lo mu ki oniroyin wa pe agba osere yii lori foonu laaaro yii, nibi to ti so pe aisan kankan ko de oun mole ati pe oun ko si nile iwosan.
O so pe loooto ni ti osere-binrin toun felomii-in ropo bee si ni ko si iro nibe pe oun saisan lakooko toun dari ere naa ti won si gbe oun loo si osibitu Saint Michael nibi toun ti lo ose meji.
O wa ni aisan naa ki i se nnkan to lagbara nnkan ti Dokita so ni ko si nnkan to se oun, isinmi nikan loun fee,bee lo tun salaye oun ko ni ikunsinu kankan lori osere,niwongba to ba dara e loju.
O wa lo akoko naa lati so pe ko-ko-koo lara oun le.

No comments:

Post a Comment

Pages