Ileewe Canadian international se idije ere idaraya onile-jile - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 14 April 2019

Ileewe Canadian international se idije ere idaraya onile-jile



 
Arabinrin Fatimo Salvador, iyawo Moshood Salvador to wa laarin obi awon omoleewe naa
 Titi di akoko taa n ko iroyin yii ni awon eeyan to wa ni agbegbe ilu Eko si n so bi idije ere idaraya onile-jile tileewe Canadian International School se, eyi to je eleekeji e se larinrin to.

Idi ti won fi n soro nipa e ni bi won se se lona to laarinrin nibi tawon obi ti kan sara sawon oluko ati oga agba ileewe naa pe won gbiyanju, won si n fee ki iru nnkan bee maa loo ni oorekoore.

Ninu oro Arabinrin Salvador, to je alakoso ileewee naa, to tun je aya agba oselu oloselu nni, Onarebu Moshood Salvador, o dupe lowo Olorun paapaa awon alakoso fere idaraya onile-jile naa fun bi won se seto ayeye lona igbalode leyii to bojumu.

O dupe lowo Olorun fun bo se n gbe ohun rere se nileewee naa, ti ilosiwaju rere si n fojoojumo ba ileewe naa, bee lo lo akoko naa lati dupe lowo oko e, Onarebu Moshood Salvador, fun atileyin ati ifowosowopo to n ri gba lati je ki idagbasoke de ba ileeewe naa ati bo se je ki oun di alakoso ileewe naa..

Bee lo tun fi idunnu e han lori ipa okan-o-jokan tawon omoleewee naa paapaa awon omo kekekee ko ninu ere idaraya naa.
Lara ere idaraya awon omo ileewe naa

 O ni nnkan ti eyi tumo si ni pe ki i se pe awon kan n ko won nipa ere idaraya lasan ati pe awon n gbero lati rii pe awon sawari awon omo ti Olorun febun ere idaraya jinki. O wa gba awon obi nimoran lati mu omo won wa sileewe Canadian International won ko si ni kabamo.

Opo awon obi to soro lojo naa ni won fi idunnu won han lori er idaraya onile-jile naa bee ni won tun so bawon oluko ileewe naa se n ko awon omo won, ati pe okan lara ileewe to dara ju nipinle Eko nileewe naa.

Awon naa wa gba awon obi yooku nimoran lati mu omo won wa sileewe naa.

No comments:

Post a Comment

Pages