Sunday Oginni, to je akowe igun kan ninu egbe oselu Labour nipinle Ogun ti gba ase lati je ki igbejo ti igbimo to n gbejo lori ibo to waye si daa igbejo duro na titi ti idajo yoo fi waye lori ejo kotemilorun to pe niluu Ibadan.
Lojo Isegun, Tusidee, ose yii ni Oginni
pe ejo kotemilorun lori bi awon igbimo to n gbejo to pe lori bi won se yo oruko
oludije won kuro ninu iwe idibo to waye losu to koja nu ti won si tewogba ti
Arabambi to je alaga igun keji fegbe oselu Labour naa wole.
Agbejoro Oginni, Kehinde Ayanwale ninu iwe ipejo to pe
naa lo ti pe igbimo to n gbejo naa lejo kotemilorun lori bi won se fagile ejo
ti olupejo e pe naa..
Oginni ninu ejo to pe ti igbimo naa
danu ko to pe kotemilorun lo ti ro awon igbimo naa lati fagile ibo to gbe Dapo
Abiodun wole, ki won si seto ibo mii in.
Sugbon Adajo Chinwe Onyeabor to saaju igbimo to n gbejo naa fagile ejo naa
lojo kesan an, osu yii nitori bi won lo se je pe ejo yii kan naa ni Arabambi to
je alaga igun keji pe eyi ti won lo tabuku ileejo naa.
Ni bayi, Akowe egbe naa, Oginni ti
pejo kotemilorun nibi to ti salaye pe ki Arabanbi to pejo loun ti pe eyi ti
nomba je EPT/OG/GOV/02/2019. O ni awon si ti san owo idabobo ti won ni kawon
san, nigba ti igbejo fee bere.
O ni bi igbimo naa ba fee da ejo nu
ti alaga egbe oselu Labour to de leyin ti nomba e je EPT/OG/GOV/03/2019 lo ye ki won da nu.
No comments:
Post a Comment