Aye iyawo mi ti n sofo fun mi bayii- Pasito Seye Senfuye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 13 April 2019

Aye iyawo mi ti n sofo fun mi bayii- Pasito Seye Senfuye




Ko seni to wa nibi ayeye idagbere ti won se fun Pasito Arabinrin Oluwayemisi Senfuye ti ori e ko nii wu lakooko ti oko e, Pasito Seye Senfuye to je oko oloogbe n soro iwuri nipa iyawo to dagbere faye, koda se lomi n jabo loju awon ti won ko le mu un mora.

Nibi ayeye naa to waye nile ijosin ile ijo isura ti Olorun iyen Treasure House of God, to wa ni  Quarry niluu Abeokuta, lojo Eti, Furaidee, Pasito Senfuye sapejuwe iyawo e gege bi Angeli ti Olorun ran soun ninu aye yii.

O ni ipa e ninu aye yii koja iyawo ati pe mama oun ni, aye e si ti n sofo bayii ninu aye oun bo tile je pe ko tii pe to faye sile. Nigba to n soro nipa bi iku se mu Oloogbe naa loo, Pasito Senfuye so pe “Ni nnkan bii ojo meedogun lo fi wa ni ese kan aye, ese kan orun nile iwosan to ti n gba itoju niluu Abuja, ti mi o  raye baa soro, gbogbo bi mo ba se n pe nomba e ko nii gbe, mo tile roo pe boya o n binu si mi, awon dokita lo wa salaye fun mi pe ko lee gbe nitori ipo to wa’

‘Sugbn leyin ojo keedgun tawon dokita ti n ba a faa, ni o pada bo saye ti won si ranse pe mi, bi mo se de ohun ti mo fee bo bata ese mi ni mo gbo ti enikan pe DF, ko si selomii in to maa n pe mi bee ju iyawo mi lo”

Ninu oro e to ba oun so gbeyin lo ni oun tii fura pe olojo ti de nigba toun bii pe ki lawon nnkan to rii lakooko ti ko fi le soro, o ni nnkan akooko to koko so ni pe Buhari lo maa wole, pe won fi ran oun, bee lo tun lo so awon irinajo to n rin lati inu lle kan bo si omii in ko taji.

Pasito Seye Senfuye sapejuwe iyawo gege bi eni to maa n fi adura ran oun lowo lakooko toun ba rin irinajo, gbogbo aso toun wo oun ko mo bi won se n fo, iyawo e yii naa ni,

Bee lo ni ni idaji koun to dide lori beedi, iyawo oun yii yoo ti ba oun pese omi ti loworo lati fi we, gbogbo awon nnkan wonyii laye e ti sofo bayii.

Lara awon to wa nibe lojo naa ni Arabinrin Kemi Adeosun, to je minisita feto isuna tele ati oko e, awon asaaju esin, awon akowe ijoba atawon eeyan pataki lo wa nibe.

No comments:

Post a Comment

Pages