Lati fi mo ise takun takun to n se nipa ka so eeyan di onile ti ara e, Ileese iwe iroyin City People fee fun oga agba ati oludasile ileese awon to n ta ile, iyen Pelican Valley Estate, Ogbeni Babatunde Adeyemo, ni awoodu nla.
Gege bi atejade to te wa lowo, leta
kan ti oga agba ileese iwe iroyin City People, Seye Kehinde, fi ranse si Babatunde Adeyemo, lojo kejo, osu
kerin, ni won fi so fun lati wa ni imurasile fun awoodu ti yoo waye lojo
kerindinlogun, osu kefa, odun yii, ni Providence Event Centre, niluu Abeokuta,.
Bi Adeyemo ba se n gba awoodu lojo
naa bee ni ileese e naa yoo tun gba ami eye gege bi ileese onile to fakoyo ju
lodun to koja.
Lara awon ti won tun reti lojo naa
ni Arabinrin Bamidele Abiodun, to je iyawo gomina ti won sese dibo yan.
Nigba to n soro nipa awoodu ti won
fee fid a lola naa, Oludasile ileeese Pelican naa so pe awoodu naa ko je ajoji
soun sugbon Pataki tileese iwe iroyin City People fee foun ati ileese e| yoo
tun fi akotun sagbara won lati ma ate siwaju nipa si so awon eeyan di onile
tiwon.
Adeyemo, to tun je oniroyin, tun salaye pe oun yoo rii
pea won sa gbogbo agbara won nileeese naa lati le mu igbe aye rorun fawon
araalu nipinle Ogun.
Bee lo wa gboriyin fun ijoba apapo
lori bi won se soju ona
reluwe , ile idanileko, itaja
igbalode sawon agbegbe kan niluu Abeokuta lati je ki ilu naa dun un wo daadaa,
to si tun mu idagbasoke ba ilu pelu.
No comments:
Post a Comment