Alagba Francis Oluseyi Adelesi, topo awon eeyan mo si Captain Tiger, to je okan lara awon agba osere tiata nipinle Ogun ti dagbere faye pe o digbose.
Gege bi a se
gbo, lojo Aje, Monde, ana an, ni baba naa ku ni Benin leyin to ti lo ogorin
odun laye.
Agba osere
tiata ti won ti wa lenu e tipe ni Baba naa, o si tun je eni to sunmo Oloye Hubert
Ogunde daadaa, nitori igbagbo ti Ogunde ni ninu e lo je ko je pe oun nikan soso
ni baba naa mu da ni lati kopa ninu fiimu MR JOHNSON ti won se niluu Jos.
Bakan naa lo
tun kopa ninu awon fiimu ti Baba Ogunde se atawon fiimu mii in ti ko lonka.
Leyin pe Captain Tiger je osere, bee lo tun je olorin, to si tun mo nipa ijo
jijo daadaa
Ose to koja yii la gbo pe Baba naa sese pe
ogorin odun. Iyawo atawon omo merin lo fi saye lo.
No comments:
Post a Comment