Gomina
to sese n kogba sile nipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun ti so pe ayeye odun
ilu lilu, eleekerin iru e, ti yoo waye laarin ojo keedogbon si ketadinlogbon
osu yii yoo tun larinrin ju awon eyi ti won ti se tele lo.
O
soro yii lakooko to n ba awon oniroyin agbaye soro, lojo Isegun, Tusidee, eyi
to waye ni gbongan Banquet, lagbegbe Mitros, Ibara, niluu Abeokuta.
Odun
ayeye ilu lilu odun yii ti won pe akori e ni ojo iwaju ilu lilu lo so pe yoo mu
awon ohun igbaani wa si iranti atii lati se iranti awon akoni, tawon nnkan ti
won se ko fi ni dohun igbagbe lojo iwaju.
O ni
lara awon nnkan ti yoo tun waye nibi ayeye naa ni ifilole ami Adire, aso Ogun,
sisi ile iranti Kuti ti won pe ni Kuti’s heritage house, idanilekoo ti yoo waye ni Olumo Rock, Wiwo
reluwe lati Iju-Ishaga ni Eko si Lafenwa niluuu Abeokuta.
Bakan
naa ni Seun Kuti, yoo tun fere da awon eeyan lola ni iranti Fela Anikulapo
Kuti.
Amosun fikun oro e pe
ayeye odun ilu lilu naa yoo je ki oro aje ipinle Ogun tun goke sii, yoo si tun
je ki asa ni igbega sii pelu bi Ojogbon Wole Soyinka naa yoo se wa nibe lojo
naa.
Ninu oro ikini ku abo
e, igbakeji gomina nipinle naa, to tun je alaga igbimo ayeye naa, Yetunde
Onanuga, so pe awon orileede mokanlelogun pelu egbe metalelogun nile Africa ni
yoo kopa nigba tawon merindinlogbon pelu egbe mokanlelaadorin lati Nigeria, bee ni won lawon olukopa tun bo ni United
Kingdom, China, Belgium, Haiti, Germany ati France.
No comments:
Post a Comment