Lojoruu, Wesidee, ni gomina tuntun ti won sese yan nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun sagbkale igbimo ti yoo jiroro nipa sise ijoba tuntun ati oro aje, eyi ti Tunde Lemo je alaga won.
Nibi ifilole naa to
waye ni gbongan TCC, to wa ni Ogere, nipinle Ogun ni Gomina tuntun naa ti gba
igbimo naa nimoran lati rii pe won sise won, ki won si je ki ero won papo mo
ohun ti erongba won da le lori iyen lati jo gbimo papo fojo iwaju, eyi ti akori
ipolongo e da le lori.
O so pe inu oun dun
pelu awon eeyan naa lori bi won se gba lati fi akoko ati iriri won sile lati
sin awon eeyan ipinle naa lori ise ti won gbe le won lowo.
Dapo Abiodun tun so pe ise to wa niwaju igbimo
atawon olubawon sise po naa ni lati satupale erongba ise ti won so pe won fee
se faraalu lakooko ti ipolongo n lo lowo, gbogbo awon eto tijoba tuntun naa ni
lokan, ki won si sise lee lori daadaa.
O so pe oun nigbagbo
ninu awon igbimo atawon ti won yoo jo sise po naa pe won yoo se ise ti won gbe
le won lowo naa daadaa, ti won yoo si mu esi rere jade nigba ti won ba n gbe
abajade won sita. y be necessary.
O fikun oro e pe
eerongba awon ni lati pese ijoba tuntun lona ti yoo pese mimu idagbasoke ba oro
aje ati lati je ki igbe aye rorun fun gbogbo mutu-muwa nipinle Ogun laifi ti
eleyameya se.
O ni akiyesi oun toun
se lakooko ipolongo kaakiri ipinle naa je koun mo toun si dupe pe awon loun
alumoni to le je ki ise rorun fawon eeyan sugbon ipenija to wa nibe ni lati fi
alafo sile laarin awon to n sise atawon to n woo niran.
Bee lo tun so di mimo
pe ijoba ti yoo bere ise ninu osu to n bo yoo tesiwaju nibi tijoba to wa lode
yii baa ba de iyen awon akanse ise ti won se lowo, ko le je iwulo fun araalu.
O ni oun nigbagbo pe
ijoba to si wa lode yii yoo fawon labo awon ibi ti won ba ise akanse de lati le
tesiwaju, nitori ijoba lo ni ohun gbogbo.
No comments:
Post a Comment