Titi di akoko ti a n ko iroyin yii lowo lawon omo egbe oselu All Progressive Party iyen APC tipinle Ogun si n so nipa bi oludije gomina labe egbe oselu naa se seru ba awon ti won jo fee dije fun ipo gomina ti yoo waye lojo Abameta, Satide, ose yii.
Nibi
ipolongo ita- gbangba egbe naa to waye ni Ake niluu Abeokuta lawon eeyan ti n
so pelu igboya pe tabi sugbon kan ko si, okunrin naa lo maa jawe olubori ninu
ibo to n bo naa.
Lati
nnkan bii aago meje aaro aaro lawon eeyan ti ro wa sibi ayeye ipolongo naa
nigba ti yoo si fi di aago mokanla aaro, awon ara Abeokuta naa ti mo pe awon
fee gbalejo nla.
Lara
awon to tun je ki ipolongo naa fi larinrin ni ti Igbakeji aare orileede yii,
Yemi Osinbajo, Oloye Olusegun Osoba, to je gomina tele nipinle Ogun, Seneto
Olamilekan Adeola topo mo si Yayi ati egbelegbe awon eeyan ni won wa nibe lojo
naa.
Ninu
oro Osinbajo, igbakeji aare lorileede yii, o ro awon omo ipinle Ogun lati dibo
fun Dapo Abiodun, gege bi won se dibo yan oun ati Aare Mohammadu Buhari wole ni
nnkan bi ose meji seyin.
O
loun nigbagbo pe egbe oselu naa ni yoo bori ninu ibo gomina ati omo ile igbimo
asofin. Bee naa ni Dapo Abiodun naa koko dupe lowo awon omo ipinle Ogun lori bi
won se dibo yan egbe won wole ninu ibo to koja.
O
wa seleri pe oun ko nii jawon nitanmo bi oun ba fi le wole ninu ibo Satide pelu
erongba lati mu gbogbo ileri oun se.
No comments:
Post a Comment