Awon onifuji fiwa toogi won han nita gbangba l’ Abeokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 6 March 2019

Awon onifuji fiwa toogi won han nita gbangba l’ Abeokuta



Ko seni to ri iwa tegbe awon omo onifuji tipinle Ogun hu lojoruu, Wesidee, ti ko se ni kayefi nnkan tawon to si wa nibe so lojo naa ni pe oju tawon eeyan fi n wo
won nigboro ni won hu lojo naa.

Gege bi a se gbo, oludije gomina labe egbe osere APM, Abdulkabir Akinlade lo se ipade po pelu awon osere nibi to ti bawon so nipa erongba e ati nnkan to ni fun won, ti won ba le dibo yan an wole. Eyi to waye ni gbongan Cultural Centre, Kuto, niiluu Abeokuta.

 Bi won se pari ipade naa ti okunrin oludiije naa fi won sile ni wahala be sile nita gbangba nigba tawon omo onifuji, eyi ti alaga egbe naa nipinle Ogun, Alaaji Taofeek Adeyinka tawon kan mo si Tobacco saaju awon yooku e loo ba awon to seto ipade naa iyen Kehinde Soaga ti won ni dandan, awon gbodo mo iye ti won gbe kale ati iye to  maa kan awon.

Kekere ko ni won pe oro naa, to di pe won bere si ni tele okunriin naa kaakiri ti won si fohun sile pe tawon ko ba ri owo gba, awon yoo da gbogbo nnkan ru ni ati pe awon yoo tun lo ba ofiisi e je.

Oniroyin wa gbo pe o fee gba won to wakati meji ki wwon to ri oro naa yanju ti won si n pariwo bi eni ti ko ni eko kaakiri pe dandan, awon gbodo gba owo gidi kuro nibe.

Sugbon ninu iwadii ti a se lati gbo pe nitori awon iwa yii ni ko je ki won pe won wa sibi eto naa, won ni ko seni to fiwe pe won wa, ayojuran nikan ni won wa se.

Leyinoreyin, won fun won ni egberun lona aadota naira sibe ko tun te won lorun pe owo naa kere, awon yoo si fa wahala ni.

Se lawon eeyan bere si nii soro kobakugbe sawon omo onifuji, won ni nnkan to ye ki won ja fun nigba ti Akinlade fun won laaye lati soro, won ko ja fun, owo ti ko nitumo ni won wa fee bo sokoto nita gbangba lati ja lee lori.

Won loro won fee idanilekoo ti won ba fee ki won maa pe won sibi nnkan gidi lojo iwaju.
  

No comments:

Post a Comment

Pages