Dapo Abiodun |
Oludije gomina labe egbe oselu APC
nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti ki alakoso gbogbogboo fun ijo Ridiimu,
Pasito E O Adeboye ku ayeye ojoobi odun ketadinlogorin to dele aye.
Ninu atejade kan ti agbenuso fun
oludije naa, Ogbeni Remmy Hasaan fi sita lo ti so pe Dapo Abiodun naa darapo mo
milionu awon eeyan ti won ba Pasito ijo Ridiimu naa sajoyo.
O so pe inu oludije naa dun ti ko si
pamora pe oun je okan lara awon to n ba Adeboye topo mo so Daddy G O, to
sapejuwe gege bi eeyan Olorun tiru e sowon laarin awon ojise Ojise Olorun
lakooko yii.
Ninu oro Abiodun lo ti so pe oun ki Baba oun ninu Oluwa Pasito
Adeboye to n se ayeye ojoobi ketadinlogorin loni in ku oriire naa. O ni gege bi
okan lara awon omo e lagbaye, inu oun dun pelu adura pe ki Olorun tubo roo ni
agbara ati emi gigun ninu ogba ajara Oluwa.
Bee lo tun gbadura akotun agbara
ninu ogo,ki awon tawon je omo e jogun ninu agbara naa.
No comments:
Post a Comment