Afaimo ki Amosun ma padanu ipo Seneto e - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 2 March 2019

Afaimo ki Amosun ma padanu ipo Seneto e
Pelu bi nnkan se n loo yii, afaimo ki Gomina Ibikunle Amosun tipinle Ogun ma padanu ipo seneto ti won won dibo yan-an wole lose to koja, nitori bi igbimo egbe naa ti won n pe ni Working Committee fegbe oselu APC niluu Abuja se kede pe awon da okunrin naa duro ninu egbe naa pelu erongba lati lee danu ninu egbe naa patapata.

Gege bi atejade ti won fi sita ni won ti salaye pe awon da Gomina naa ati akegbe e nipinle Imo iyen Gomina Okorocha duro lori iwa agabagebe ti won n hu ninu egbe naa lati odun to koja.

Bee ni won tun gbe siwaju awon alase egbe naa pelu amoran lati le awon mejeeji danu, nitori gbogbo iwa ko kan mi tawon mejeeji n hu ko ba ofin egbe mu, to si je pe kaka ki won jawo, se lo tun peleke sii fun won ni.

Latigba ti egbe lapapo si kede idaduro Gomina Amosun ni egbe APC tipinle Ogun ti soro sita pe idaduro ko nikan lawon n fee, ki won le okunrin naa danu ninu egbe APC ni yoo bojumu.

Ninu atejade kan ti Ogbeni Tunde Oladunjoye, to je akowe olupolongo egbe naa fi sita lana an, ojo Eti, Furaide, lo ti salaye pe igbese ti National Working Committee  iyen NWC naa gbe lo ye ko ti waye tipe.

Atejade naa tun ka bayii ‘Gbogbo igbese ti Gomina Amosun gbe lo je ti alaimoore, to si tun je agabagebe egbe, awa pe igbimo NWC egbe naa lati te siwaju ninu igbese won, ki won si lee danu patapata, eyi ni yoo je eko fun un lojo iwaju atawon to ba tun fee se awokose e.

Sugbon bi nnkan se n tun ti wa n lo, bi egbe ba fi le le Amosun danu ninu egbe naa, o se e se ki won gba tiketi to fi wole fun ipo seneto lose to koja, ki won si gbe fun elomin in.

A tie gbo pe won ti ni ki Seneto Lanre Tejuoso to si wa nipo naa lowolowo, ko maa murasile. Amo sa, ibi ti oro ere ori itage tegbe oselu APC se n lowo yoo fidi si ko tii seni to le so.

No comments:

Post a Comment

Pages