Ibo gomina ku dede; Won lawon omo egbe oselu ADC fegbe sile bo si APC. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 27 February 2019

Ibo gomina ku dede; Won lawon omo egbe oselu ADC fegbe sile bo si APC.


Gboyega Nasir Isiaka 
Bi nnkan se n loo yii, erongba Gboyega Nasir Isiaka lati di gomina ipinle Ogun maa bo si ofo ninu ibo gomina to n bo lojo kesan an, osu keta, odun yii nitori bi won se lawon omo egbe oselu ADC ti okunrin naa ti jade dije se n bo si egbe oselu APC fun ibo to n bo lona naa.
 
Gege bi iwadii oniroyin wa, ko to di pe won dibo aare to koja yii la gbo pe won lawon kan ninu egbe pinnu lati fegbe naa sile ti won si dibo fun oludije egbe APC.

Won ni ti ki i  ba se bee ni, egbe oselu naa ko ba rowo mu ju bi won se ri muu lo yii ati pe ibo asoju-sofin kan soso ti won mu ninu ibo Satide, to koja naa, ori lo ba won se.

A tun gbo pe titi di akoko ti a n ko iroyin yii, opo awon to ti fi GNI lokanbale pe oun lawon yoo fun ni ibo won, ti yi oun won pada, to si je pe ariwo egbe oselu APC ni won mu bonu bayii.

Koda lara awon ti won gbe apoti ibo labe egbe oselu naa ti won fidi remi ni won so pe won ti gba lati sise fun APC, ti won so pe won ko fee fu oludije won lara ti won yoo fi di ibo ti won fee di naa.

Ni bayii, idaniloju ko tii si fun egbe oselu ADC ninu ibo naa, nitori APC lawon omo egbe won fee sise fun un, ti won ni won si ti bere.

No comments:

Post a Comment

Pages