Akowe olupolongo kiatika fegbe oselu APC nipinle Ogun, Ogbeni
Tunde Oladujoye ti so pe ohun to le mu ki ibo gomina to n bo lojo kesan an, osu
to n bo yii, fi le seso rere ni a fi ti won ba gbe komisanna fawon olopaa
nipinle Ogun, Ahmed Iliyasu kuro nipinle naa, nitori awon eeyan ko nigbagbo
ninu e, nitori awon nnkan to ti se seyin latigba ti oselu ti bere.
Okunrin naa
soro yii lakooko to n bawon oniroyin kan soro loni in, niluu Abeokuta. O so pe
awon ko nigbagbo ninu oga olopaa naa lati pese abo fun ibo naa, nitori oro e ko
yato seni to ti gbabode.
O so pe o se
ni laaanu pe lati ojo Abameta, Satide, ti ibo waye ti won pa olopaa kan lona
Ilaro, iyalenu lo je pe komisanna naa ko ti ri eyo enikan mu lori isele naa.
Bakan naa ni
akowe olupolongo fegbe oselu naa tun fi ti igba ti aare orileede yii, Mohammadu
Buhari, wa si Abeokuta, tawon kan ju bata ati omi mo on losan an gan-an ti
komisanna awon olopaa ko si le so pe iye bayii lawon mu lori oro naa.
Akowe
olupolongo naa so pe pelu bi nnkan si se n lo yii, eru n bawon, idi niyii tawon
fi ke si ijoba apapo lati ko awon soja wa sipinle Ogun fun ibo gomina to n bo
naa.
O ni ki i se
pe kawon soja naa wa ni agbegbe ti won ti fee dibo sugbon ki won fi won pamo
sawon ibi ti ko jinna si ibudo, nitori tawon kan ba fee ji apoti ibo gbe.
O ni ti ki i
ba se pe Iliyasu Ahmed ni eru ofin labe kilode ti won gbe e kuro nipinle Ogun
to fi ake kori pe oun ko lo, nitori e lo se ye kawon araalu gan an mo pe
nnkankan wa labele nidi oro e.
Nipa oro ti
Amosun so pe oun setan lati bere ipongo gomina fun Akinlade latinu egbe APM, Okunrin
naa so pe lakooko awon dupe lowo awon araalu fun bi won se tu jade dibo dun
egbe oselu APC, nibi ti Buhari ti jawe olubori.
O ni ibo ti
won di nipinle Ogun tun je ki ibo aare naa tun loo soke, bee lo tun dupe lowo
awon eeyan Ogun Central lori bi won se gboro si Oloye Olusegun Osoba lenu, ti
won fi dibo yan Amosun wole.
O ni ki won
fi Amosun sile pelu riru ofin egbe to n se nitori oun mo pe lagbara Olorun egbe
APC lo maa wole ibo gomina. O ni egbe oselu APM to n gbe seyin kaakiri, o ni
sebi won fidi remi, ibo won ni Ogun Central ko to ida meje ninu ida ogorun un
pelu bi won se nawo sita to.
Oladunjoye
so pe awon ko ti ri ti Amosun ro bayii nitori ibo to wa lona lawon si n sise le
lori to si daju pe didun ni osan yoo so lojo kesan- an, osu to n bo.
O ni to ba
ya awon olori egbe niluu Abuja yoo gbe igbese to ba ye feni to ba dale.
No comments:
Post a Comment