Fun
ilosiwaju ede Yoruba ati igbelaruge asa ati isese, awon onimo ise iroyin ti won
n gbe iroyin jade lede Yoruba sinu ero alatagba, iyen (internet) ti da egbe
tuntun sile bayii, ti won si pe e ni League of Yoruba Online Media.
Ninu oro okan lara oludasile egbe naa, Omooba Aderounmu
Kazeem lo ti so pe, “Ohun kan pataki to mu wa da egbe yii sile ni bi ede
abinibi wa; ti a fi n gbe iroyin sita ko se ni i parun, ti igbelaruge nla yoo
tubo de ba e, ti awa ti a fi n gbe iroyin jade paapaa yoo samulo e lona ti yoo
fiwa han gege bi omoluabi ti iran Yoruba n se.”
Aderounmu, eni ti se oludasile, Magasinni Alore fi kun un wi
pe, ona kan pataki ti a tun le ko awon eeyan ni ede abinibi wa ni gbigbe iroyin
sita pelu ede ohun, eyi ti yoo fun won lanfaani lati maa pade awon ewa ede
lorisirisi ninu iroyin ti won ba n ka, ti yoo si tun je akagbadun fun won
paapaa.
Lara awon ileese iroyin ti won wa lori ero alatagba ti won
je omo egbe yii ni, Iroyin Ojutole; Bo Se Ri; Awikonko, Magasinni Alore;
Magasinni Asejere atawon mi-in bakan naa.
Egbe yii ti wa fidi e mule wi pe, gbogbo ilana to to, to si
ba eto iroyin yii mu ni awon omo egbe naa n tele ninu ojuse won, ati pe
ilosiwaju iran Yoruba ati orile-ede yii lapapo gan-an lo je awon logun nipa
lilo ede Yoruba lati fi gbe ojulowo iroyin jade.
No comments:
Post a Comment