Egbe oselu APC nipinle Ogun ti dupe
lowo gbogbo awon araalu fun bi won se tu jade lopo dibo won lati fi gbe Aare
Mohammadu wole leekeji ati bawon omo egbe naa ko se yeye Amosun jade pelu
gbogbo iwa arifin ati afojudi to ti hu si won seyin.
Oro yii jade ninu atejade kan ti
akowe olupolongo kiatika egbe naa, Ogbeni Tunde Oladunjoye, fi sita nibe lo ti
fi idunnu e han sawon oludibo paapaa awon asaaju egbe naa lati gba Amosun la
lowo itiju ayeraye ti won ko baa ko si.
Ninu oro to wa nibe lo ti ni ko si
nnkan meji tawon le se ju pe kawon dupe gidigidi fun bi ibo naa se gbe Buhari
atawon oludije won yooku wole.
O ni ‘ Adupe lowo gbogbo awon eeyan
to wa ni agbegbe Ogun Central ti won je omoleyin fun Oloye Olusegun Osoba lori
bi won se gboro sii lenu fun pe ki won ma wo nnkan ti Amosun se, ki won dibo
won fun un, ti won si se bee.
O ni pelu gbogbo iwoye won tawon se
bi ki i ba se egbe oselu APC, se ni Amosun ko ba fidi remi pelu ibo egberun
mewaa ati mejidinlogoji.
O ni edun okan lo je pe pelu bi APM se
nawo to, won tun fidi remi gan an ni pelu ida meje ninu ida ogorun un ti won ni
nibi ibo naa. O nibi kan soso ti won ti wole asoju-sofin nibi ti won ti pa
olopaa.
Oladunjoye wa lo anfaani ninu
atejade naa lati bebe fun atileyin awon araalu leekan si fun ibo gomina ti yoo
waye lojo kesan an osu keta, lati tun fi ibo won gbe Dapo Abiodun wole latinu
egbe oselu APC wole.
No comments:
Post a Comment