Bi nnkan se n loo yii o se e se ki
Abiodun Ajayi to ti figba kan je alaga ijoba ibile fun Abeokuta South ko jade dije fun ipo asoju-sofin fun
ekun agbegbe Abeokuta South labe egbe oselu PDP ninu ibo to n bo, oun si ni won
ni won fee lo lati dipo Owolabi Kola Balogun,OKB, to fegbe naa sile loseto
koja.
Okunrin yii la gbo pe o se ipo keji
lakooko ti won se ibo pamari ninu egbe naa nibi ti Owolabi ti jawe olubori.Awon
to sunmo okunrin naa ni won fi to oniroyin wa leti pe eto ti n lo labele lati
ba okunrin naa soro, ko si koju ipenija naa.
Bo tile je pe titi di akoko yii, a
ko tii gbo boya okunrin naa gba si won lenu tabi ko gba labe egbe oselu PDP.
Ohun taa n gbo ni pe adura won ni pe
ki okunrin naa ko gba si won lenu nitori won ni to ba fi le gba, o se e se ki
nnkan yi pada lagbo oselu lagbegbe naa, nitori awon eeyan agbegbe ti setan lati
satileyin fun un nitori awon ise to ti se si wa nibe, ti won ko le gbagbe.
Bee la tun gbo pe okunrin alaga
ijoba ibile tele naa tit un opo igbe aye awon eeyan e naa si nipase eto eko, ilera,
abo ati oro-aje.
Ogbeni Azeez Kufile, okan lara awon
eeyan to n gbe lagbegbe Itoko, okan lara ibi ti won ni ki Ajayi ti wa jade dije
to ba oniroyin wa soro so pea won eeyan to wa ni Abeokuta South lo fife won han
si okunrin naa lati wa jade dupo.
Okunrin naa so pe bo se kawon lo be
Ajayi awon setan lati loo dobale fun un lati jade dupo nitori awon ise asesile
to ti se, O ni oloselu to maa n wa ona lati mu iyato bawon eeyan ni okunrin
naa.
No comments:
Post a Comment