Oluyele akobi Tunji Braithwaite ti jade laye o - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 12 February 2019

Oluyele akobi Tunji Braithwaite ti jade laye o



Ogbeni Oluyele Folahan Braithwaite, to je akobi agba oloselu, to tun je  agba agbejoro ti jade laye o.

Gege bi atejade ti aburo oloogbe naa, Olumide Braithwaite fi sita, lo ti so pe okunrin naa to da ijo Restore Church of Christ sile lo so pe o dagbere faye leyin to ti lo odun mejilelogota laye.

Won so pe okunrin naa ni ti aisan foni-ku- fola- dide lara, ko to di pe elemi- in gba pelu aisan okan ti won lo yo o lenu lojiji, to si dake si osibitu Lagos Island.

Won lokunrin naa loo sileewe girama CMS grammar school, bee lo tun loo si Mill field, ni oke- okun, England, won lo tun kawe ni yunifasiti Ahmadu Bello  ati yunifasiti Buckingham, England nibi to ti kawe gba imo ijinle nipa ofin.

Iyawo pelu awon omobinrin ti won je ibeji ni okunrin naa fi saye lo.


No comments:

Post a Comment

Pages