Ibo ku dede; Egbe oselu Labour ati AD ti foribale fun Otegbeye. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 14 February 2019

Ibo ku dede; Egbe oselu Labour ati AD ti foribale fun Otegbeye.


 
Bo tile je pe ibo ti ku si dede ti yoo waye o ti fi han daju pe
awon oludije fegbe oselu Labour ati AD fun ibo asoju-sofin fun agbegbe Yewa  South/Ipokia ti foribale fun oludije fegbe oselu APC iyen Agbejoro Biyi Otegbeye, ti won si ti gba lati fibo gbe e wole.

Gege bi iwadii wa, lojo Isegun, Tusidee, ose yii ni Onarebu Odun Adeleye to je oludije fegbe oselu Labour ti so pe oun ko se mo, to si ti fi atileyin e han si Otegbeye lati baa sise po.

O so pe oun gbe igbese naa nitori ife toun ni si Otegbeye pelu igbagbo pe yoo tubo mu idagbasoke ba ekun naa to ba wole. O tun so pe oun mo pe okunrin naa ni iran gidi fawon eeyan naa, idi niyii toun fi so igba toun dojo iwaju.

Bakan naa lo ro gbogbo omo egbe oselu Labour to wa ni agbegbe naa lati jade lojo Satide, ose yii ki won si fibo won gbe Otegbeye wole.

Bawon egbe oselu Labour se pari todo tiwon ni egbe oselu AD, agbegbe naa so pe awon naa ti setan lati fatileyin won han si Otegbeya fun ibo to n bo naa.

Ninu oro Omooba Adegbemi Adeogun to je alaga fegbe oselu naa nijoba ibile Yewa South lawon naa so pe ki Otegbeye fokanbale nitori oun lawon yoo fun ni ibo won lojo naa, nitori pe awon mo pe o kaju e.

Won lawon gbe igbese naa nitori bi oludije ti won faa kale se so pe oun ko se mo. Alaga naa war o gbogbo omo egbe naa lati dibo asoju-sofin won fun Otegbeye lojo Satide yii.

Ninu oro e, Agbejoro Biyi Otegbeye dupe lowo awon egbe oselu mejeeji fun ipinnu won lati sise po pelu oun, o wa seleri pe oun ko ni doju ti won.
No comments:

Post a Comment

Pages