E gba mi lowo ajo INEC O, Ki won fun mi ni kaadi idibo mi- Paseda - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 14 February 2019

E gba mi lowo ajo INEC O, Ki won fun mi ni kaadi idibo mi- Paseda


 
Oludije fegbe oselu SDP nipinle Ogun, Otunba Rotimi Paseda ti ke si ajo eleto idibo lorileede yii, lati wa kaadi idibo oun sita, nitori boun ko se ri gba, ko oun lominu titi di akoko yii.

O soro yii lakooko to n bawon oniroyin soro lojoruu, Wesidee, ose to koja, o ni pelu bi nnkan se n loo yii, o fee dabi eni pe oun ko fee nigbagbo ninu ajo naa fun ibo to n bo naa.

Oludije naa so pe gbogbo igbese to ye koun gbe lati gba kaadi idibo naa lo ja si pabo, nitori boun ko se ri gba, eyi to tumo si pe won ko fee koun kopa ninu awon ibo to n bo lona naa.

Okunrin naa salaye pe’ Lojo ti mo fee loo foruko sile fun kaadi ibo, awa mejila ninu ebi mi la jo loo foruko sile, sugbon o ya mi lenu pe gbogbo awon yooku ti ri gba, emi nikan ni mi o ti rii gba’

O tun fidi oro e mule nipa sisa afihan iwe to fi foruko sile ti nomba e je 27-17-14-003 ati VIN: 90F5-B159- 6641- 6087-233, o ni eyi loun fi dibo lodun 2015 laisi ariwo.

O tun so pe  "Ninu osu kejo, odun 2018, mo rii pe kaadi naa ti fee maa baje, eyi to mu mi lati gbe igbese lati gba mii in, Mo loo si ofiisi INEC office to wa ijoba ibile Odogbolu nibi ti omidan Akinwande,  ti gba ojulowo leyin ti mo se eda e, to si gba mi niyanju lati pada wa gba tuntun’

O ni siyalenu oun,oun ti n para ofiisi naa ni Odogbolu lati gba kaadi PCV naa titi di akoko toun bawon oniroyin soro, oun ko ri gba.

Paseda ni pelu nnakan to sele yii, ko je koun nigbagbo ninu ajo INEC fun ise ti won gbe si won niwaju, o ni bawo ni kaadi toun lo fi dibo lodun 2015 toun fee lo lati dije fun ipo gomina ninu ibo to n bow a poora ninu akosile won, ati pe bawo ni kaadi idanimo iru eeyan bi toun se le di awaari.

O wa ni eyi tumo sip e ajo naa n gbiyanju lati seeru ninu ibo to n bo naa nipinle Ogun.

O wa lo akooko naa lati ke si alaga fajo eleto idibo, Ojogbon Mahmood Yakubu lati ke si awon to ba wa nikawo e lati wa kaadi naa jade foun lati dibo.No comments:

Post a Comment

Pages