Titi di akoko ti a n ko iroyin yii
lowo ni wahala n loo labele lori bawon egbe osere tiata TAMPAN se gbe idaji
milionu naira kale fun iranwo won lori ipolongo Buhari lati di aare orileede
yii leekeji.
Gege bi a se gbo, lose to koja lawon
oloye egbe naa lapapo ti Ogbeni Bolaji Amusan, topo mo si Mista Latin to je
aare egbe naa saaju atawon agba egbe naa loo fun Ogbeni Raji Fasola, to ti
figba kan je gomina nipinle Eko, to tun je minisita foro ise bayii ni sowedowo
idaji milionu naa.
Latigba ti iroyin naa ti jade
sigboro la gbo pe wahala ti be sile ninu egbe naa ti won si n foko oro ranse si
ara won pe ariwo pe ko sowo ninu egbe naa wo ni won maa n pa kaakiri.
Ati pe o se je Buhari lawon oga won
yii lo fun lowo, niwongba to je pe ki i se gbogbo won lo wa ninu we egbe APC,
ki lo de ti won ko fi seru e fawon oludije yooku.
Won ni eyi to tumo si pe igbese lati
ta egbe osere TAMPAN fawon oloselu lati maa ri won lo nilokulo.Okan lara awon
agba osere egbe naa to ba wa soro so pe meloo ninu awon omo egbe naa ni won ti
dide iranlowo sii, sebi won lo maa n foruko eni ti nnkan ba se toro owo kaakiri
ni.
Won ni ona lati tun fo egbe si wewe
lakooko Latin ni won tun baa bo ati pe o ye ki aare egbe naa dara e yato
gedegbe si oselu sugbon oun gan-an ko se bee, nibi ti won ba dari e si lo n lo.
Oniroyin wa so pe bo tile je pe ona
lati wole si Buhari lara to ba wole eleekeji ni won n da sugbon awon to ba wa soro
pe iro pata, apo ara won ni won n ja si, won kan fee maa lo oruko egbe lasan ni
tabi ki idaniloju pe eni ti won ro yoo wole eleekeji.
Bi a si ti n so lowo yii, oro naa ko
ti nii yanju epe la gbo pe won fi ranse si ara won.
No comments:
Post a Comment