Baba Suwe so pe; E gba mi o, asiko iku mi ko tii to, mo saisan gidigidi. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 19 February 2019

Baba Suwe so pe; E gba mi o, asiko iku mi ko tii to, mo saisan gidigidi.


 Latigba ti iyawo gbajumo osere alawada nni, Omoladun ti ku ni nnkan ko ti fe bee danmoran foko e, Alaaji Babatunde Omidina, topo awon ololufe e mo si Baba Suwe, orisiirisii nnkan ni won so nigboro nipa okunrin naa.

Opo igba ni won ti so pe ara okunrin naa ko ya sugbon tawon tie so pe ko si nnkan to joo, Ni bayii, oro ti wa foju han pe ara Baba Suwe ko ya gidigidi, to si n fee iranlowo awon araalu.

Nibi to le de okunrin naa ti pariwo sita lori eto agba sorosoro kan, Ogbeni Kola Olootu niluu Ibadan nibe lo ti ni kawon eeyan maa woo un niran, ki won ma je koun ku, nitori asiko iku oun ko tii to.

Ninu alaye e lori eto ohun lojo yen lo ti so pe, “Orile-ede Amerika ni mo lo, bi mo se dohun-un, ti won n ki mi kaabo, lojiji ni mo daku, osibitu gan-an ni mo ti laju, ti mo n wo o wi pe nibo ni mo wa yii. Ose meta ni mo lo ni osibitu yen tawon eeyan n wa wo mi.
“Ni gbogbo igba ti mo wa l’Amerika yen, ko seeyan kan bayii to fe ran mi lowo, ariwo ko sowo, ko sowo ni kaluku won n pa. Nibe naa ni mo ti pinnu lati pada si Nigeria ki awon eeyan le mo nnkan to n se mi,”

Baba Suwe so pe ni kete ti oun de Nigeria ni aisan naa yiwo, nitori latigba yen losere tiata yii ti so pe oun ko le rin mo lai lo opa.

O fi kun oro e pe, “Latigba ti mo ti de si Nigeria ni mo ti n daamu kiri, bo tile je pe mi o le rin daadaa, sibe mo si n wa ona abayo si isoro yii, sugbon wahala nla ni mo n koju, nitori ko seni to fe ran mi lowo, ariwo ko sowo ko sowo lawon eeyan n pa. Ohun ti mo fe ki awon omo Nigeria ati gbogbo ololufee mi kaakiri agbaye se fun mi ni bi maa se ri owo pada si Amerika lati lo toju ara mi nibe.

“Gbogbo nnkan ti won ba fun mi pata, ni maa fi toju ara mi, ki emi naa le pada senu ise mi. Mi o ki n se arugbo rara o, ko ye ki n ti maa lo opa lati fi rin, aisan to n se mi lo fa a.”   
Pelu omije loju ni okunrin alawada yii fi so bi wahala ohun se bere. O ni, “Ti omode ba ri mi, ti agbalagba ba ri mi, ibeere kan naa ni gbogbo won n bi mi, won ni se loooto ni mo gbe kokeeni, bee emi ko gbe nnkankan. Gbogbo igbe ti mo ya pata ni won yewo ti won ko ri nnkankan nibe. Odindi ose kan ni won fi n sayewo igbe kiri, ti won ko ri nnkankan nibe.

“Nigba ti won mu mi, ori aga ni mo n sun, ti mo ba maa jeun, ounje naa ko ni i lo lenu mi, nise ni won n gbe mi kiri osibitu, ti won n ye eje wo, ti won n ye igbe wo, titi to fi dori omi ara mi.

Nise ni won n da mi ribo-ribo, ti won ko wahala gidi ba mi, nibe gan-an ni gbogbo wahala yii ti bere, nitori won fooro emi mi gan-an ni o, bee ni won ko ri ohunkohun lara mi.”
Baba Suwe fi kun oro e pe, owo ti ile-ejo ni ki ajo NDLEA fun oun, iyen milionu meedogbon naira, owo gba-ma-binu, o ni kobo lo kere ju ninu owo ohun, ijoba ko won ko fun oun.”

Ninu oro e naa lo ti so pe iku ojiji to pa agbejoro oun, Oloogbe Bamidele Atutu pelu ohun to tubo ko idaamu nla ba oun.

O ni, “Lojoojumo ni mo maa n sunkun lori iku ojiji to pa okunrin yen, nitori kani ko ku ni, oro mi ko ni i ri bayii. Wahala oro mi gan-an pelu ohun to pa a, nitori ofiisi lo ku si, o kawo lori aga kan ni ofiisi e ni, nibe ni iku ti ba a. A jo lo sinku e ni, ki Olorun ba mi foriji i.”

Baba Suwe ti ke si gbogbo eeyan pata lati dide soro oun. O ni, “Mo fi Olorun be yin, e ran mi lowo, e ma je ki n ku bayii. Owo repete ni won so pe maa nilo fun itoju mi, iyekiye ti kaluku ba ni, e fi ran mi lowo, e ma je ki n ku bayii.”

 Fun gbogbo eni to ba fe ran Baba Suwe Omidina, alawada lowo le fi owo sowo si akaunti ikowosi yii: Babs Omidina Comedy, 2003537811, First Bank Plc.


No comments:

Post a Comment

Pages