Ajo INEC fose kan kun ojo esin APC-PDP ipinle Ogun- Malik Ibitoye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 21 February 2019

Ajo INEC fose kan kun ojo esin APC-PDP ipinle Ogun- Malik Ibitoye



Egbe oselu PDP tipinle Ogun ti so pe bajo eleto ibo lorileede yii see fi ose kan kun ibo aare to ye ko waye lopin ose to koja tun sun ojo esin egbe oselu APC to ye ko to siwaju si ose kan.

Ninu atejade kan ti akowe olupolongo fegbe oselu PDP nipinle naa,  Alaaji Malik Ibitoye  fi sita lo ti so pe kawon araalu ni suuru fose kan ti won fi kun un eyi ti yoo waye lojo Satide, ose yii, nitori gbogbo ogbon ti won n da lo ye awon.

O salaye pe oro ti foju han gbangba pe egbe oselu APC ko tii setan fun ibo to n bo naa. 

Iyalenu lo so pe o si je pe alaga fajo INEC, Ojogbon Yakubu Mahmood le gbe igbese ti won gbe lojiji nigba tawon araalu ti n murasile fun ibo naa, ti won si sun un siwaju, ibanilokanje lo so pe o je.

Malik ni' Ohun to ye fun alaga Ajo INEC ni lati koko pe aare Buhari ko to di pe o kede pe awon sun eto idibo naa siwaju laarin oru to kede yen'

O ni iru nnkan bee ko waye lakooko ti Jonathan to he PDP sejoba lodun 2015, nitori pe kii saarin oru ti ibo wole ni won sun siwaju nigba naa.

Akowe olupolongo so pelu idaniloju pe egbe oselu PDP ti Bayo Dayo je alaga won nipinle Ogun ti murasile fun ibo naa to si nireti won yoo gbegba oroke nipinle naa.

Bee lo fikun atejade naa pe oludije awon fun ipo gomina, Seneto Buruji Kashamu naa ti setan fun ibo gomina to n bo ninu osu keta, odun yii, fun ti Ogun odun ijoba tiwa-n-tiwa lorileede yii.

Ibitoye wa pari oro e pe kawon omo orileede yii ni suuru di ojo Satide, ose yii ti won sun ibo naa si lati fibo won le APC lo pelu idaniloju pe ko ni si magomago ninu ibo naa.
https://ssl.gstatic.com/ui/v1/icons/mail/no_photo.png











No comments:

Post a Comment

Pages