Egbe oselu oselu All Progressives
Congress (APC), nipinle Ogun ti pariwo sita pe gbogbo ona ti Gomina Amosun fee
fi gbabode fun Aare orileede yii. Mohammadu Buhari ninu ibo aare ti yoo waye
lola lawon ti gbo.
Ninu atejade kan ti Ogbeni Tunde
Oladunjoye, to je akowe olupolongo fegbe naa fi sita lana-an lo ti salaye pe
gbogbo igbese lati maa je ki Buhari ri ibo mu daadaa ni ekun Ijebu ati Yewa, ni
won lokunrin naa sise le lori.
Gege bi atejade naa se wi, o ni awon
ipade loorekoore lo ti n lo lowo bayii larin Amosun lati nnkan bi ose meta
seyin, to si fee lo omo baba Ijebu, to dije gomina labe egbe oselu PDP sugbon
ti ko ri tikeeti e gba, oun lo ni won so pe Gomina naa fee lo lati ba nnkan je
fun ibo aare ati omo ile igbimo asofin to fee waye lola naa.
Oladunjoye so pe egberun lona igba
naira ni won ni gomina gbe kale lopin ose to koja ti ibo naa koko fee waye lati
rii pe Buhari ko ribo mu daadaa ni ekun naa nibi ti igbakeji aare orileede yii,
Yemi Osinbajo ti wa, ko fi le doju tii.
Akowe olupolongo fegbe oselu APC tun
mu wa si iranti pe laipe yii ni oludije to ti jakule fun tiketi gomina ti koko
pariwo nibio to ti bu Osinbajo pe o wa lara awon to n da wahala sile ninu
egbe awon.
Okunrin naa lo tun so pe o tun tako
ara e laipe yii pe oun si nigbagbo pe ajo INEC yoo si daruko oun gege bi
oludije fegbe to wa.
Oladunjoye ni ara ipinnu won naa ni
igbese to ni won gbe nigba ti Monsuru Sorunke, ti je alaga ijoba ibile
idagbasoke Abeokuta North-West saaju awon toogi lojo isegun, Tuside ose yii lo sibi eto kan ti won pe ni
“TraderMoni” ti won si daa ru. n”.
Bee lo ni gomina yii naa lo yari pe
awon agunbaniro kan ni won gbodo gbe loo si Ogun West nibi ti Chief Olu
Odebiyi, ti dije fun ipo seneto labe egbe oselu APC.
O wa pari oro e pe awon ro ijoba
apapo lati kilo fun Amosun ko ma baa da wahala tagbara ko nii ka sipinle Ogun..
No comments:
Post a Comment