Titi di
akoko ti a n ko iroyin yii lowo, inu adura lawon ebi akowe ijoba ipinle Ogun,
Agbejoro Taiwo Adeoluwa wa nitori bi won se ni okunrin naa wa ni ese kan aye,
ese kan orun ni osibitu FMC to wa ni Idi- Aba nibi to ti n gba itoju lowo, fun
ti ijanba moto to waye ni ale yii nibi
ti okan lara awon oludamoran gomina ti
padanu emi e.
Gege bi a se
gbo, lagbegbe kan ti won n pe ni Kobape nijoba ibile Obafemi Owode, ni won ni
ijamba naa ti waye, nibi ti won ni Omooba Adesanya tawon kan mo si ore gomina
ti padanu emi e.
Bo tile je pe titi di akoko ti a n ko iroyin yii
jo, a ko le so pato nnkan to sokunfa ijamba naa sugbon a gbo pe bisele naa se
waye ni won ti gbe won loo si osibitu FMC ni Idi- Aba fun itoju.
Iwadii tun
fi ye wa pe nigba ti oro ko fee wo mo, ni won gbe akowe ijoba naa loo sibi ti
won ti n toju awon oni pajawiri ni osibitu naa, amo ti won ko fee ki enikeni mo
ibe.
Ni nnkan bii
aago mejo abo ale yii ti oniroyin wa debe, a sakiyesi pe dereba to wa moto naa,
ara e ti n bale bee ni won so pe iye akowe ijoba naa ti n soji diedie, pelu
ireti pe laipe yii ara e yoo bo sipo.
A tun gbo pe won ti gbe oku ore gomina to
padanu emi e loo si mosuari sugbon bi gbogbo yooku ba se n loo, a o maa fi to
yin leti, sugbon loro kan ore Gomina Amosun ti je Olorun ni pe nigba ti Taiwo
Adeoluwa si n gba itoju lowo.
No comments:
Post a Comment