Oludije fun ipo gomina labe egbe
oselu APC nipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti dupe gidigidi lowo awon omo
ipinle Ogun nitori bi won se jade dibo fun aare Mohammadu Buhari nibi ibo to waye
lojo Abameta, Satide, ose yii.
Ninu atejade ti agbenuso fun oludije
naa, Onarebu Remmy Hassan fi sita lo ti fi idunnu e fawon araalu lojo Sannde. O
so pe ohun iyi lo je fegbe oselu naa lati jawe olubori , o ni eyi fihan pe won
so nigbagbo ninu egbe oselu naa.
O ni pelu bi won se ti n ko awon ibo
naa jo, gbogbo esi tawon ti gbo fihan pe ibo ti Buhari fi leke ki i se kekere,
o ni bee naa ni egbe oselu APC tun gbegba oroke ninu ibo asoju, ati
asoju-sofin, nibi ti Dapo Abiodun naa ti jawe olubori nijoba ibile e, ibo to si
fi ju awon iyooku e lo, ki i se kekere.
Remmy Hassan wa fikun oro e pe pelu
bi nnkan se loo ti ibo gomina ku dede ko waye lojo kesan, osu keta, o ni
idaniloju wa pe awon eeyan yoo tun satileyin lati fi ibo won gbe Dapo Abiodun
naa wole gege bi gomina ipinle Ogun.
O so pe ijoba APC nijoba apapo ati
tipinle yoo te siwaju nipa awon ise idagbasoke won gege bi won se seleri e ati
pe erongba Dapo Abiodun ni lati tubo je ki irorun de ba araalu. O wa ro
Muhammadu Buhari lati tete bere si nii gbe igbese lati mu ileri e se fawon
eeyan ipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment